Bẹ́ẹ̀ Mósè sì gbẹ́ òkúta wàláà méjì bí ti àkọ́kọ́, ó sì gun orí òkè Sínáì lọ ní kùtùkùtù òwúrọ̀, gẹ́gẹ́ bí OLÚWA ti pa á láṣẹ fún-un; Ó sì gbé òkúta wàláà méjèèjì náà sí ọwọ́ rẹ̀.
Ẹni tí ó ń pa ìfẹ́ mọ́ fún ẹgbẹ̀rún (1000), ó sì ń dárí jin àwọn ẹni búburú, àwọn ti ń sọ̀tẹ̀ àti elẹ́sẹ̀. Ṣíbẹ̀ kì í fi àwọn ẹlẹ́bi sílẹ̀ láìjìyà; Ó ń fi ìyà jẹ ọmọ àti àwọn ọmọ wọn fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba dé ìran kẹta àti ìkẹrin.”
Ó wí pé, “OLÚWA, bí èmi bá rí ojú rere rẹ, nígbà náà jẹ́ kí OLÚWA lọ pẹ̀lú wa. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ènìyàn ọlọ́rùn líle ni wọn, dárí búburú àti ẹ̀ṣẹ̀ wa jìn, kí o sì gbà wá gẹ́gẹ́ bí ìní rẹ.”
Nígbà náà ni OLÚWA wí pé: “Èmi dá májẹ̀mú kan pẹ̀lú yín. Níwájú gbogbo ènìyàn rẹ èmi yóò se ìyanu, tí a kò tí ì ṣe ní orílẹ̀ èdè ní gbogbo ayé rí. Àwọn ènìyàn tí ìwọ ń gbé láàrin wọn yóò rí i bí iṣẹ́ tí èmi OLÚWA yóò ṣe fún ọ ti ní ẹ̀rù tó
“Má a sọ́ra kí ẹ má se bá àwọn ènìyàn tí ń gbé ilẹ̀ náà dá májẹ̀mú; nígbà tí wọ́n bá ń se àgbérè tọ òrìsà wọn, tí wọ́n sì rúbọ sí wọn, wọn yóò pè yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ ẹbọ wọn.
Nígbà tí ìwọ bá yàn nínú àwọn ọmọbìnrin wọn fún àwọn ọmọkùnrin rẹ ní ìyàwó, àwọn ọmọbìnrin wọ̀nyí yóò se àgbérè tọ òrìsà wọn, wọn yóò sì mú kí àwọn ọmọkùnrin yín náà se bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́.
“Àjọ àkàrà àìwú ni kí ìwọ máa pamọ́. Fún ọjọ́ méje ni ìwọ yóò jẹ àkàrà aláìwú, gẹ́gẹ́ bí èmi ti pa á láṣẹ fún ọ. Ṣe èyí ní ìgbà tí a yàn nínú osù Ábíbù, nítorí ní osù náà ni ẹ jáde láti Éjíbítì wá.
Àkọ́bí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ ni kí ìwọ kí ó fi ọ̀dọ́ àgùntàn rà padà, ṣùgbọ́n bí ìwọ kò bá rà á padà, dá ọrùn rẹ̀. Ra gbogbo àkọ́bí ọkùnrin rẹ padà. “Ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ wá ṣíwájú mi ní ọwọ́ òfo.
Èmi yóò lé orílẹ̀ èdè jáde níwájú rẹ, èmi yóò sì mú kí ìpín rẹ fẹ̀, ẹnikẹ́ni kì yóò gba ilẹ̀ rẹ nígbà tí ìwọ bá gòkè lọ ní ìgbà mẹ́ta lọ́dún kọ̀ọ̀kan láti farahàn níwájú OLÚWA Ọlọ́run rẹ.
Ṣùgbọ́n nígbàkígbà tí ó bá wà níwájú OLÚWA láti bá a sọ̀rọ̀, á sí ìbòjú náà títí yóò fi jáde. Nígbà tí ó bá sì jáde, á sì sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ohun tí a ti pa láṣẹ fún-un,