Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| MOSE si pè apejọ gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli, o si wi fun wọn pe, Wọnyi li ọ̀rọ ti OLUWA palaṣẹ pe, ki ẹnyin ki o ṣe wọn. |
| 2 |
| Ijọ́ mẹfa ni ki a fi ṣe iṣẹ, ṣugbọn ijọ́ keje ni yio ṣe ọjọ́ mimọ́ fun nyin, ọjọ́ isimi ọ̀wọ si OLUWA: ẹnikẹni ti o ba ṣe iṣẹ ninu rẹ̀ li a o lupa nitõtọ. |
| 3 |
| Ẹnyin kò gbọdọ da iná ni ile nyin gbogbo li ọjọ́ isimi. |
| 4 |
| Mose si sọ fun gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli pe, Eyi li ohun ti OLUWA palaṣẹ, wipe, |
| 5 |
| Ẹnyin mú ọrẹ wá lati inu ara nyin fun OLUWA: ẹnikẹni ti ọkàn rẹ̀ fẹ́, ki o mú u wá, li ọrẹ fun OLUWA; wurà, ati fadakà, ati idẹ; |
| 6 |
| Ati aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ didara, ati irun ewurẹ; |
| 7 |
| Ati awọ àgbo ti a sè ni pupa, ati awọ seali, ati igi ṣittimu; |
| 8 |
| Ati oróro fun fitila, ati olõrùn fun oróro itasori, ati fun turari didùn; |
| 9 |
| Ati okuta oniki, ati okuta ti a o tò si ẹ̀wu-efodi, ati si igbàiya. |
| 10 |
| Gbogbo ọlọgbọ́n inú ninu nyin yio si wá, yio si wá ṣiṣẹ gbogbo ohun ti OLUWA palaṣẹ; |
| 11 |
| Ibugbé na, ti on ti agọ́ rẹ̀, ati ibori rẹ̀, kọkọrọ rẹ̀, ati apáko rẹ̀, ọpá rẹ̀, ọwọ̀n rẹ̀, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀; |
| 12 |
| Apoti nì, ati ọpá rẹ̀, itẹ́-ãnu nì, ati aṣọ-ikele na; |
| 13 |
| Tabili na, ati ọpá rẹ̀, ati ohun-èlo rẹ̀ gbogbo, ati àkara ifihàn nì; |
| 14 |
| Ati ọpà-fitila na fun titanna, ati ohun-elo rẹ̀, ati fitila rẹ̀, pẹlu oróro fun titanna. |
| 15 |
| Ati pẹpẹ turari, ati ọpá rẹ̀, ati oróro itasori, ati turari didùn, ati aṣọ-sisorọ̀ fun ẹnu-ọ̀na, ani atiwọle ẹnu agọ́ na; |
| 16 |
| Ati pẹpẹ ẹbọsisun, ti on ti àwọn oju-àro idẹ rẹ̀, ati ọpá rẹ̀, ati gbogbo ohun-èlo rẹ̀, agbada na ti on ti ẹsẹ rẹ̀; |
| 17 |
| Aṣọ-isorọ̀ ti agbalá, ọwọ̀n rẹ̀, ati ihò-ìtẹbọ rẹ̀, ati aṣọ-isorọ̀ fun ẹnu-ọ̀na agbalá na; |
| 18 |
| Ekàn agọ́ na, ati ekàn agbalá na, ati okùn wọn; |
| 19 |
| Aṣọ ìsin wọnni, lati sìn ni ibi mimọ́, aṣọ mimọ́ wọnni fun Aaroni alufa, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀, lati ma fi ṣe iṣẹ alufa. |
| 20 |
| Gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli si lọ kuro ni iwaju Mose. |
| 21 |
| Nwọn si wá, olukuluku ẹniti ọkàn rẹ́ ru ninu rẹ̀, ati olukuluku ẹniti ọkàn rẹ̀ mu u fẹ́, nwọn si mú ọrẹ OLUWA wá fun iṣẹ agọ́ ajọ na, ati fun ìsin rẹ̀ gbogbo, ati fun aṣọ mimọ́ wọnni. |
| 22 |
| Nwọn si wá, ati ọkunrin ati obinrin, iye awọn ti ọkàn wọn fẹ́, nwọn si mú jufù wá, ati oruka-eti, ati oruka-àmi, ati ilẹkẹ wurà, ati onirũru ohun ọṣọ́ wurà; ati olukuluku enia ti o nta ọrẹ, o ta ọrẹ wurà fun OLUWA. |
| 23 |
| Ati olukuluku enia lọdọ ẹniti a ri aṣọ-alaró, ati elesè àluko, ati ododó, ati ọ̀gbọ daradara, ati irun ewurẹ, ati awọ àgbo pupa, ati awọ seali, mú wọn wá. |
| 24 |
| Olukuluku ẹniti o ta ọrẹ fadakà ati idẹ, o mú ọrẹ OLUWA wá: ati olukuluku enia lati ọdọ ẹniti a ri igi ṣittimu fun iṣẹkiṣẹ ìsin na, mú u wá. |
| 25 |
| Ati gbogbo awọn obinrin ti iṣe ọlọgbọ́n inu, nwọn fi ọwọ́ wọn ranwu, nwọn si mú eyiti nwọn ran wá, ti alaró, ati ti elesè-àluko, ati ti ododó, ati ti ọ̀gbọ daradara. |
| 26 |
| Ati gbogbo awọn obinrin inu ẹniti o ru soke li ọgbọ́n nwọn ran irun ewurẹ. |
| 27 |
| Ati awọn ijoye mú okuta oniki wá, ati okuta ti a o tò, fun ẹ̀wu-efodi nì, ati fun igbàiya nì; |
| 28 |
| Ati olõrùn, ati oróro; fun fitila, ati fun oróro itasori, ati fun turari didùn. |
| 29 |
| Awọn ọmọ Israeli ta ọrẹ atinuwa fun OLUWA; olukuluku ọkunrin ati obinrin, ẹniti ọkàn wọn mu wọn fẹ́ lati mú u wá fun onirũru iṣẹ, ti OLUWA palaṣẹ ni ṣiṣe lati ọwọ́ Mose wá, |
| 30 |
| Mose si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Wò o, OLUWA ti pè Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀ya Judah, li orukọ. |
| 31 |
| O si fi ẹmi Ọlọrun kún u li ọgbọ́n, li oyé, ni ìmọ, ati li onirũru iṣẹ-ọnà; |
| 32 |
| Ati lati humọ̀ alarabara iṣẹ, lati ṣiṣẹ ni wurà, ati ni fadakà, ati ni idẹ, |
| 33 |
| Ati li okuta gbigbẹ́ lati tò wọn, ati ni igi fifin, lati ṣiṣẹ li onirũru iṣẹ-ọnà. |
| 34 |
| O si fi sinu ọkàn rẹ̀ lati ma kọni, ati on, ati Oholiabu, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀ya Dani. |
| 35 |
| O si fi ọgbọ́n inu kún wọn, lati ṣe onirũru iṣẹ, ti alagbẹdẹ, ati ti ọnà, ati ti agunnà, li aṣọ-alaró, ati li elesè-àluko, li ododó, ati li ọ̀gbọ daradara, ati ti ahunṣọ, ati ti awọn ẹniti nṣe iṣẹkiṣẹ ati ti awọn ẹniti nhumọ̀ iṣẹ-ọnà. |
|
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/exodus/035.mp3
40
35