Wọ́n fi aṣọ aláwọ̀ aró, ati ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa, rán ẹ̀wù aláràbarà tí àwọn alufaa yóo máa wọ̀ ninu ibi mímọ́ náà fún Aaroni gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.
Ó fi òòlù lu wúrà, ó sì gé e tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ bí okùn, wọ́n fi ṣe iṣẹ́ ọnà sára aṣọ aláwọ̀ aró ati ti elése àlùkò ati aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́.
Wọ́n tọ́jú àwọn òkúta onikisi, wọ́n jó wọn mọ́ ojú ìtẹ́lẹ̀ wúrà, wọ́n kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli sí ara wọn, bí wọ́n ti máa ń kọ orúkọ sí ara òrùka èdìdì.
Irú aṣọ tí wọ́n fi ṣe efodu náà ni wọ́n fi ṣe ìgbàyà rẹ̀, wọ́n fi wúrà, aṣọ aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò, aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe iṣẹ́ ọnà sí i lára.
Oríṣìí òkúta mejila ni ó wà níbẹ̀; orúkọ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn dúró fún orúkọ ẹ̀yà àwọn ọmọ Israẹli kọ̀ọ̀kan, wọ́n dàbí èdìdì, wọn sì kọ orúkọ àwọn ẹ̀yà Israẹli mejeejila sí wọn lára, òkúta kan fún ẹ̀yà kan.
Òrùka aṣọ ìgbàyà yìí ni wọ́n fi dè é mọ́ òrùka ara efodu pẹlu aṣọ aláwọ̀ aró tẹ́ẹ́rẹ́ kan, kí ó lè sùn lé àmùrè efodu náà tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára, kí ìgbàyà náà má baà tú kúrò lára efodu, gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.
Wọ́n fi aṣọ aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò, ati aṣọ pupa ati aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́ ṣe àwòrán èso Pomegiranate sí etí ẹ̀wù àwọ̀kanlẹ̀ náà nísàlẹ̀.
Wọ́n fi aṣọ funfun onílà tẹ́ẹ́rẹ́tẹ́ẹ́rẹ́, ti aláwọ̀ aró, ti elése àlùkò ati aṣọ pupa tí wọ́n ṣe iṣẹ́ ọnà sí lára ṣe àmùrè gẹ́gẹ́ bí OLUWA ti pàṣẹ fún Mose.
Wọ́n sì gbé àgọ́ àjọ náà tọ Mose wá, àgọ́ náà ati gbogbo àwọn ohun èlò inú rẹ̀, àwọn ìkọ́ rẹ̀, àwọn àkànpọ̀ igi inú rẹ̀, àwọn igi ìdábùú inú rẹ̀, àwọn òpó rẹ̀, ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn;
Bẹ́ẹ̀ náà ni aṣọ títa ti àgbàlá náà, àwọn òpó rẹ̀ ati àwọn ìtẹ́lẹ̀ wọn, ati aṣọ fún ẹnu ọ̀nà àgọ́ náà, okùn rẹ̀ ati àwọn èèkàn rẹ̀, ati gbogbo ohun èlò fún ìsìn ninu àgọ́ mímọ́ náà, ati fún àgọ́ àjọ náà.
Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ẹ̀wù tí a ṣe oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ọnà sí fún iṣẹ́ ìsìn àwọn alufaa ninu ibi mímọ́, ẹ̀wù mímọ́ fún Aaroni alufaa ati ẹ̀wù fún àwọn ọmọ rẹ̀ náà, tí wọn yóo fi máa ṣe iṣẹ́ wọn bí alufaa.