Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| ỌMỌ mi, bi iwọ ba ṣe onigbọwọ fun ọrẹ́ rẹ, bi iwọ ba jẹ́ ẹ̀jẹ́ fun ajeji enia. |
| 2 |
| Bi a ba fi ọ̀rọ ẹnu rẹ dẹkùn fun ọ, bi a ba fi ọ̀rọ ẹnu rẹ mu ọ. |
| 3 |
| Njẹ, sa ṣe eyi, ọmọ mi, ki o si gbà ara rẹ silẹ nigbati iwọ ba bọ si ọwọ ọrẹ́ rẹ; lọ, rẹ ara rẹ silẹ, ki iwọ ki o si tù ọrẹ́ rẹ. |
| 4 |
| Máṣe fi orun fun oju rẹ, tabi õgbe fun ipenpeju rẹ. |
| 5 |
| Gbà ara rẹ bi abo agbọnrin li ọwọ ọdẹ, ati bi ẹiyẹ li ọwọ apẹiyẹ. |
| 6 |
| Tọ ẽrùn lọ, iwọ ọlẹ: kiyesi iṣe rẹ̀ ki iwọ ki o si gbọ́n: |
| 7 |
| Ti kò ni onidajọ, alabojuto, tabi alakoso. |
| 8 |
| Ti npese onjẹ rẹ̀ ni igba-ẹ̀run, ti o si nkó onjẹ rẹ̀ jọ ni ìgba ikore. |
| 9 |
| Ọlẹ, iwọ o ti sùn pẹ to? nigbawo ni iwọ o dide kuro ninu orun rẹ? |
| 10 |
| Orun diẹ si i, õgbe diẹ si i, ikawọkòpọ lati sùn diẹ: |
| 11 |
| Bẹ̃ni òṣi rẹ yio de bi ẹniti nrìn àjo, ati aini rẹ bi ọkunrin ti o hamọra ogun. |
| 12 |
| Enia-kenia, ọkunrin buburu, ti o nrìn ti on ti ẹnu arekereke. |
| 13 |
| O nṣẹju rẹ̀, o nfi ẹsẹ rẹ̀ sọ̀rọ, o nfi ika rẹ̀ ṣe ajuwe; |
| 14 |
| Arekereke mbẹ li aiya rẹ̀, o humọ ìwa-ika nigbagbogbo; o ndá ija silẹ. |
| 15 |
| Nitorina ni ipọnju rẹ̀ yio de si i lojiji; ojiji ni yio ṣẹ́ laini atunṣe. |
| 16 |
| Ohun mẹfa li Oluwa korira: nitõtọ, meje li o ṣe irira fun ọkàn rẹ̀: |
| 17 |
| Oju igberaga, ète eke, ati ọwọ ti nta ẹ̀jẹ alaiṣẹ silẹ, |
| 18 |
| Aiya ti nhumọ buburu, ẹsẹ ti o yara ni ire sisa si ìwa-ika, |
| 19 |
| Ẹlẹri eke ti nsọ eke jade, ati ẹniti ndá ìja silẹ larin awọn arakunrin. |
| 20 |
| Ọmọ mi, pa aṣẹ baba rẹ mọ́, ki iwọ ki o má si ṣe kọ̀ ofin iya rẹ silẹ: |
| 21 |
| Dì wọn mọ aiya rẹ nigbagbogbo, ki iwọ ki o si so o mọ ọrùn rẹ. |
| 22 |
| Nigbati iwọ ba nrìn, yio ma ṣe amọ̀na rẹ; nigbati iwọ ba sùn, yio ma ṣọ ọ; nigbati iwọ ba si ji, yio si ma ba ọ sọ̀rọ. |
| 23 |
| Nitoripe aṣẹ ni fitila; ofin si ni imọlẹ; ati ibawi ẹkọ́ li ọ̀na ìye: |
| 24 |
| Lati pa ọ mọ́ kuro lọwọ obinrin buburu nì, lọwọ ahọn ìpọnni ajeji obinrin. |
| 25 |
| Máṣe ifẹkufẹ li aiya rẹ si ẹwà rẹ̀; bẹ̃ni ki o má si ṣe jẹ ki on ki o fi ipenpeju rẹ̀ mu ọ. |
| 26 |
| Nitoripe nipasẹ agbere obinrin li enia fi idi oniṣù-akara kan: ṣugbọn aya enia a ma wá iye rẹ̀ daradara. |
| 27 |
| Ọkunrin le gbé iná lé aiya rẹ̀ ki aṣọ rẹ̀ ki o má jona? |
| 28 |
| Ẹnikan ha le gun ori ẹyin-iná gbigbona, ki ẹsẹ rẹ̀ ki o má jona? |
| 29 |
| Bẹ̃li ẹniti o wọle tọ obinrin ẹnikeji rẹ̀ lọ; ẹnikẹni ti o fi ọwọ bà a, kì yio wà li ailẹṣẹ̀. |
| 30 |
| Nwọn ki igàn ole, bi o ba ṣe pe, o jale lati tẹ́ ọkàn rẹ̀ lọrùn, nigbati ebi npa a; |
| 31 |
| Ṣugbọn bi a ba mu u, yio san a pada niwọ̀n meje; gbogbo ini ile rẹ̀ ni yio fi san ẹsan. |
| 32 |
| Ṣugbọn ẹni ti o ba ba obinrin ṣe panṣaga, oye kù fun u: ẹniti o ba ṣe e yio pa ẹmi ara rẹ run. |
| 33 |
| Ọgbẹ ati àbuku ni yio ni; ẹ̀gan rẹ̀ kì yio si parẹ́ kuro. |
| 34 |
| Nitori owú ni ibinu ọkunrin: nitorina kì yio dasi li ọjọ ẹsan. |
| 35 |
| On kì yio nani owo idande, bẹ̃ni inu rẹ̀ kì yio yọ́, bi iwọ tilẹ sọ ẹ̀bun di pipọ. |
|
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/proverbs/006.mp3
31
6