|
| 1 |
|
| ỌMỌ mi, pa ọ̀rọ mi mọ́, ki o si fi ofin mi ṣe ìṣura ṣura pẹlu rẹ. |
|
| 2 |
|
| Pa ofin mi mọ́, ki iwọ ki o si yè; ati aṣẹ mi bi ọmọloju rẹ. |
|
| 3 |
|
| Dì wọn mọ ika rẹ, kọ wọn si wala aiya rẹ. |
|
| 4 |
|
| Wi fun ọgbọ́n pe, Iwọ li arabinrin mi; ki o si pe oye ni ibatan rẹ obinrin: |
|
| 5 |
|
| Ki nwọn ki o le pa ọ mọ́ kuro lọwọ obinrin ẹlomiran, lọwọ ajeji ti nfi ọ̀rọ rẹ̀ ṣe ipọnni. |
|
| 6 |
|
| Li oju ferese ile mi li emi sa bojuwò lãrin ferese mi. |
|
| 7 |
|
| Mo si ri ninu awọn òpe, mo kiyesi ninu awọn ọmọkunrin, ọmọkunrin kan ti oye kù fun, |
|
| 8 |
|
| O nkọja lọ ni igboro li eti igun ile rẹ̀; o si lọ si ọ̀na ile rẹ̀, |
|
| 9 |
|
| Ni wiriwiri imọlẹ, li aṣãlẹ, li oru dudu ati òkunkun: |
|
| 10 |
|
| Si kiyesi i, obinrin kan pade rẹ̀, o wọ aṣọ panṣaga, alarekereke aiya. |
|
| 11 |
|
| (O jẹ alariwo ati alagidi; ẹsẹ rẹ̀ kì iduro ni ile rẹ̀. |
|
| 12 |
|
| Nisisiyi o jade, nisisiyi o wà ni igboro, o si mba ni ibi igun ile gbogbo.) |
|
| 13 |
|
| Bẹ̃li o dì i mu, o si fẹnu kò o li ẹnu, o si fi ọ̀yájú wi fun u pe, |
|
| 14 |
|
| Ọrẹ́, alafia mbẹ lọwọ mi, loni ni mo ti san ẹjẹ́ mi. |
|
| 15 |
|
| Nitorina ni mo ṣe jade wá pade rẹ, lati ṣe afẹri oju rẹ, emi si ri ọ. |
|
| 16 |
|
| Emi ti fi aṣọ titẹ ọlọnà tẹ́ akete mi, ọlọnà finfin ati aṣọ ọ̀gbọ daradara ti Egipti. |
|
| 17 |
|
| Emi ti fi turari olõrùn didùn ti mirra, aloe, ati kinnamoni si akete mi. |
|
| 18 |
|
| Wá, jẹ ki a gbà ẹkún ifẹ wa titi yio fi di owurọ, jẹ ki a fi ifẹ tù ara wa lara. |
|
| 19 |
|
| Nitoripe bãle kò si ni ile, o re àjo ọ̀na jijin: |
|
| 20 |
|
| O mu àsuwọn owo kan lọwọ rẹ̀, yio si de li oṣupa arànmọju. |
|
| 21 |
|
| Ọ̀rọ rẹ̀ daradara li o fi mu u fẹ, ipọnni ète rẹ̀ li o fi ṣẹ́ ẹ li apa. |
|
| 22 |
|
| On si tọ̀ ọ lọ lẹsẹkanna bi malu ti nlọ si ibupa, tabi bi aṣiwere ti nlọ si ibi ọgbọ́n ìfabà kọ́. |
|
| 23 |
|
| Titi ọfà fi gún u li ẹ̀dọ̀; bi ẹiyẹ ti nyara bọ sinu okùn, ti kò si mọ̀ pe fun ẹmi on ni. |
|
| 24 |
|
| Njẹ nisisiyi, ẹnyin ọmọ, ẹ feti si temi, ki ẹ si fiye si ọ̀rọ ẹnu mi. |
|
| 25 |
|
| Máṣe jẹ ki aiya rẹ̀ ki o tẹ̀ si ọ̀na rẹ̀, máṣe ṣina lọ si ipa-ọ̀na rẹ̀. |
|
| 26 |
|
| Nitori ọ̀pọlọpọ enia li o ṣá lulẹ; nitõtọ ọ̀pọlọpọ alagbara enia li a ti ọwọ rẹ̀ pa. |
|
| 27 |
|
| Ile rẹ̀ li ọ̀na ọrun-apadi, ti nsọkalẹ lọ si iyẹwu ikú. |
|
|
: |
| 1 | | 2 | | 3 | | 4 | | 5 | | 6 | | 7 | | 8 | | 9 | | 10 | | 11 | | 12 | | 13 | | 14 | | 15 | | 16 | | 17 | | 18 | | 19 | | 20 | | 21 | | 22 | | 23 | | 24 | | 25 | | 26 | | 27 | 1
1
1 |
|
|---|
|
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/proverbs/007.mp3
31
7