Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| ỌGBỌ́N ti kọ́ ile rẹ̀, o si gbẹ́ ọwọ̀n rẹ̀ meje: |
| 2 |
| O ti pa ẹran rẹ̀; o ti ṣe àdalu ọti-waini rẹ̀; o si ti tẹ́ tabili rẹ̀. |
| 3 |
| O ti ran awọn ọmọbinrin rẹ̀ jade, o nke lori ibi giga ilu, pe, |
| 4 |
| Ẹnikẹni ti o ṣe òpe ki o yà si ihin: fun ẹniti oye kù fun, o wipe, |
| 5 |
| Wá, jẹ ninu onjẹ mi, ki o si mu ninu ọti-waini mi ti mo dàlu. |
| 6 |
| Kọ̀ iwere silẹ ki o si yè; ki o si ma rìn li ọ̀na oye. |
| 7 |
| Ẹniti o ba ba ẹlẹgàn wi, yio gba itiju fun ara rẹ̀, ati ẹniti o ba ba enia buburu wi yio gbà àbuku rẹ̀. |
| 8 |
| Máṣe ba ẹlẹgàn wi, ki o má ba korira rẹ, ba ọlọgbọ́n enia wi, yio si ma fẹ ọ. |
| 9 |
| Fi ẹkọ́ fun ọlọgbọ́n enia, yio si ma gbọ́n siwaju, kọ́ enia olõtọ, yio si ma fẹ ọ. |
| 10 |
| Ibẹ̀ru Oluwa ni ipilẹṣẹ ọgbọ́n: ati ìmọ Ẹni-Mimọ́ li oye. |
| 11 |
| Nitori nipasẹ mi li ọjọ rẹ yio ma lé si i, ati ọdun ìye rẹ yio si ma lé si i. |
| 12 |
| Bi iwọ ba gbọ́n, iwọ o gbọ́n fun ara rẹ: ṣugbọn bi iwọ ba iṣe ẹlẹgàn, iwọ nikan ni yio rù u. |
| 13 |
| Alaroye li aṣiwere obinrin: òpe ni kò si mọ̀ nkan. |
| 14 |
| O sa joko li ẹnu-ọ̀na ile rẹ̀, lori apoti, ni ibi giga ilu. |
| 15 |
| Lati ma pè awọn ti nkọja nibẹ, ti nrìn ọ̀na ganran wọn lọ: pe, |
| 16 |
| Ẹnikẹni ti o ba ṣe òpe, ki o yà si ìhin: ẹniti oye kù fun, o wi fun u pe, |
| 17 |
| Omi ole dùn, ati onjẹ ikọkọ si ṣe didùn. |
| 18 |
| Ṣugbọn on kò mọ̀ pe awọn okú wà nibẹ: ati pe awọn alapejẹ rẹ̀ wà ni isalẹ ọrun-apadi. |
|
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/proverbs/009.mp3
31
9