Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| ORUKỌ rere dara jù ororo ikunra; ati ọjọ ikú jù ọjọ ibi enia lọ. |
| 2 |
| O dara lati lọ si ile ọ̀fọ jù ati lọ si ile àse: nitoripe eyi li opin gbogbo enia; alãye yio si pa a mọ́ li aiya rẹ̀. |
| 3 |
| Ibinujẹ san jù ẹrín: nitoripe nipa ifaro oju a si mu aiya san. |
| 4 |
| Aiya ọlọgbọ́n mbẹ ni ile ọ̀fọ; ṣugbọn aiya aṣiwère ni ile iré. |
| 5 |
| O san lati gbọ́ ibawi ọlọgbọ́n jù ki enia ki o fetisi orin aṣiwère. |
| 6 |
| Nitoripe bi itapàpa ẹgún labẹ ìkoko, bẹ̃li ẹrín aṣiwère: asan li eyi pẹlu. |
| 7 |
| Nitõtọ inilara mu ọlọgbọ́n enia sinwin; ọrẹ a si ba aiya jẹ. |
| 8 |
| Opin nkan san jù ipilẹṣẹ rẹ̀ lọ: ati onisuru ọkàn jù ọlọkàn igberaga. |
| 9 |
| Máṣe yara li ọkàn rẹ lati binu, nitoripe ibinu simi li aiya aṣiwère. |
| 10 |
| Iwọ máṣe wipe, nitori kili ọjọ iṣaju ṣe san jù wọnyi lọ? nitoripe iwọ kò fi ọgbọ́n bere niti eyi. |
| 11 |
| Ọgbọ́n dara gẹgẹ bi iní, ati nipasẹ rẹ̀ ère wà fun awọn ti nri õrùn. |
| 12 |
| Nitoripe ãbò li ọgbọ́n, ani bi owo ti jẹ́ abò: ṣugbọn ère ìmọ ni pe, ọgbọ́n fi ìye fun awọn ti o ni i. |
| 13 |
| Wò iṣẹ Ọlọrun: nitoripe, tali o le mu eyini tọ́ ti on ṣe ni wiwọ? |
| 14 |
| Li ọjọ alafia, mã yọ̀, ṣugbọn li ọjọ ipọnju, ronu pe, bi Ọlọrun ti da ekini bẹ̃li o da ekeji, niti idi eyi pe ki enia ki o máṣe ri nkan ti mbọ̀ lẹhin rẹ̀. |
| 15 |
| Ohun gbogbo ni mo ri li ọjọ asan mi: olõtọ enia wà ti o ṣegbé ninu ododo rẹ̀, ati enia buburu wà ti ọjọ rẹ̀ pẹ ninu ìwa buburu rẹ̀. |
| 16 |
| Iwọ máṣe ododo aṣeleke; bẹ̃ni ki iwọ ki o máṣe fi ara rẹ ṣe ọlọgbọ́n aṣeleke: nitori kini iwọ o ṣe run ara rẹ? |
| 17 |
| Iwọ máṣe buburu aṣeleke, bẹ̃ni ki iwọ ki o má ṣiwère; nitori kini iwọ o ṣe kú ki ọjọ rẹ ki o to pe? |
| 18 |
| O dara ki iwọ ki o dì eyi mu; pẹlupẹlu iwọ máṣe yọ ọwọ rẹ kuro ninu eyi: nitori ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun ni yio yọ kuro ninu rẹ̀ gbogbo. |
| 19 |
| Ọgbọ́n mu ọlọgbọ́n lara le jù enia alagbara mẹwa lọ ti o wà ni ilu. |
| 20 |
| Nitoriti kò si olõtọ enia lori ilẹ, ti nṣe rere ti kò si dẹṣẹ. |
| 21 |
| Pẹlupẹlu máṣe fiyesi gbogbo ọ̀rọ ti a nsọ; ki iwọ ki o má ba gbọ́ ki iranṣẹ rẹ ki o bu ọ. |
| 22 |
| Nitoripe nigba pupọ pẹlu li aiya rẹ mọ̀ pe iwọ tikalarẹ pẹlu ti bu awọn ẹlomiran. |
| 23 |
| Idi gbogbo wọnyi ni mo fi ọgbọ́n wá; mo ni, emi o gbọ́n: ṣugbọn ọ̀na rẹ̀ jin si mi. |
| 24 |
| Eyi ti o jinna, ti o si jinlẹ gidigidi, tali o le wá a ri? |
| 25 |
| Mo fi aiya mi si i lati mọ̀, on ati wadi, on ati ṣe afẹri ọgbọ́n ati oye, on ati mọ̀ ìwa buburu wère, ani ti wère ati ti isinwin: |
| 26 |
| Mo si ri ohun ti o korò jù ikú lọ, ani obinrin ti aiya rẹ̀ iṣe idẹkun ati àwọn, ati ọwọ rẹ̀ bi ọbára: ẹnikẹni ti inu Ọlọrun dùn si yio bọ lọwọ rẹ̀; ṣugbọn ẹlẹṣẹ li a o ti ọwọ rẹ̀ mu. |
| 27 |
| Kiyesi i, eyi ni mo ri, bẹ̃li oniwasu wi, ni wiwadi rẹ̀ li ọkọkan lati ri oye. |
| 28 |
| Ti ọkàn mi nwakiri sibẹ, ṣugbọn emi kò ri: ọkunrin kanṣoṣo ninu ẹgbẹrun ni mo ri; ṣugbọn obinrin kan ninu gbogbo awọn wọnni, emi kò ri. |
| 29 |
| Kiyesi i, eyi nikanṣoṣo ni mo ri, pe, Ọlọrun ti da enia ni iduroṣinṣin; ṣugbọn nwọn ti ṣe afẹri ihumọkihumọ. |
|
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/ecclesiastes/007.mp3
12
7