Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| NIBO ni olufẹ rẹ lọ, iwọ arẹwà julọ ninu awọn obinrin? nibo li olufẹ rẹ yà si? ki a le ba ọ wá a. |
| 2 |
| Olufẹ mi sọkalẹ lọ sinu ọgba rẹ̀, si ebè turari, lati ma jẹ̀ ninu ọgbà, ati lati ká itanna lili. |
| 3 |
| Emi ni ti olufẹ mi, olufẹ mi si ni ti emi: o njẹ̀ lãrin itanna lili. |
| 4 |
| Iwọ yanju, olufẹ mi, bi Tirsa, o li ẹwà bi Jerusalemu, ṣugbọn o li ẹ̀ru bi ogun pẹlu ọpagun. |
| 5 |
| Mu oju rẹ kuro lara mi nitori nwọn bori mi: irun rẹ si dabi ọwọ́ ewurẹ ti o dubulẹ ni Gileadi. |
| 6 |
| Ehin rẹ dabi ọwọ́ agutan ti ngòke lati ibi iwẹ̀ wá, ti olukuluku wọn bi ìbejì, kò si si ọkan ti o yàgan ninu wọn. |
| 7 |
| Bi ẹ̀la eso-pomegranate kan ni ẹrẹkẹ rẹ ri lãrin iboju rẹ. |
| 8 |
| Ọgọta ayaba ni mbẹ, ati ọgọrin àle, ati awọn wundia lainiye. |
| 9 |
| Ọkan ni adaba mi, alailabawọn mi; on nikanṣoṣo ni ti iya rẹ̀, on ni ãyo ẹniti o bi i. Awọn ọmọbinrin ri i, nwọn si sure fun u; ani awọn ayaba ati awọn àle, nwọn si yìn i. |
| 10 |
| Tali ẹniti ntàn jàde bi owurọ, ti o li ẹwà bi oṣupa, ti o mọ́ bi õrun, ti o si li ẹ̀ru bi ogun pẹlu ọpagun? |
| 11 |
| Emi sọkalẹ lọ sinu ọgba eso igi, lati ri awọn ẹka igi tutu afonifoji, ati lati ri bi ajara ba ruwe, ati bi igi-granate ba rudi. |
| 12 |
| Ki emi to mọ̀, ọkàn mi gbe mi ka ori kẹkẹ́ Amminadibu. |
| 13 |
| Pada, pada, Ṣulamite; pada, pada, ki awa ki o le wò ọ. Ẽṣe ti ẹnyin fẹ wò Ṣulamite bi ẹnipe orin ijó Mahanaimu. |
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/songofsolomon/006.mp3
8
6