Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| ATI li ọjọ na iwọ o si wipe, Oluwa, emi o yìn ọ: bi o tilẹ ti binu si mi, ibinu rẹ ti yi kuro, iwọ si tù mi ninu. |
| 2 |
| Kiyesi i, Ọlọrun ni igbala mi; emi o gbẹkẹle, emi ki yio si bẹ̀ru: nitori Oluwa Jehofah li agbara mi ati orin mi; on pẹlu si di igbala mi. |
| 3 |
| Ẹnyin o si fi ayọ̀ fà omi jade lati inu kanga igbala wá. |
| 4 |
| Li ọjọ na li ẹnyin o si wipe, Yìn Oluwa, kepe orukọ rẹ̀, sọ iṣẹ́ rẹ̀ lãrin awọn enia, mu u wá si iranti pe, orukọ rẹ̀ li a gbe leke. |
| 5 |
| Kọrin si Oluwa: nitori o ti ṣe ohun didara: eyi di mimọ̀ ni gbogbo aiye. |
| 6 |
| Kigbe, si hó, iwọ olugbe Sioni: nitori ẹni titobi ni Ẹni-Mimọ́ Israeli li ãrin rẹ. |
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/isaiah/012.mp3
66
12