Ati ogo ẹwà, ti o wà lori afonifoji ọlọra, yio jẹ itanna rirọ, gẹgẹ bi eso ti o yara ṣaju igba ìkore; eyiti nigbati ẹniti o ba nwò o ba ri, nigbati o wà li ọwọ́ rẹ̀ sibẹ, o gbe e mì.
Ṣugbọn awọn pẹlu ti ti ipa ọti-waini ṣìna, ati nipa ọti-lile nwọn ti ṣako; alufa ati wolĩ ti ṣìna nipa ọti-lile, ọti-waini mu wọn daradara, nwọn di aṣako nipa ọti-lile, nwọn ṣìna ninu iran, nwọn kọsẹ ni idajọ.
Nitorina ọ̀rọ Oluwa jẹ aṣẹ le aṣẹ, aṣẹ le aṣẹ fun wọn: ẹsẹ le ẹsẹ, ẹsẹ le ẹsẹ; diẹ nihin, diẹ lọhun: ki nwọn ba le lọ, ki nwọn si ṣubu sẹhin, ki nwọn si ṣẹ́, ki a si dẹ wọn, ki a si mu wọn.
Nitori ẹnyin ti wipe, Awa ti ba ikú dá majẹmu, a si ti ba ipò-okú mulẹ: nigbati pàṣan gigun yio là a já, kì yio de ọdọ wa: nitori awa ti fi eké ṣe ãbo wa, ati labẹ irọ́ li awa ti fi ara wa pamọ:
Nitorina bayi li Oluwa Jehofah wi, pe, Kiyesi i, emi gbe okuta kan kalẹ ni Sioni fun ipilẹ, okuta ti a dán wò, okuta igun-ile iyebiye, ipilẹ ti o daju: ẹniti o gbagbọ kì yio sá.
Nitori Oluwa yio dide bi ti oke Perasimu, yio si binu gẹgẹ bi ti afonifoji Gibeoni, ki o ba le ṣe iṣẹ rẹ̀, iṣẹ àrà rẹ̀; yio si mu iṣe rẹ̀ ṣẹ, ajeji iṣe rẹ̀.
Njẹ nitorina, ẹ máṣe jẹ ẹlẹgàn, ki a má ba sọ ìde nyin di lile; nitori emi ti gbọ́ iparun lati ọdọ Oluwa, Oluwa awọn ọmọ-ogun wá, ti o ti pinnu lori gbogbo ilẹ.
Nigbati on ti tẹ́ ojú rẹ̀ tan, on kò ha nfunrugbìn dili, ki o si fọn irugbìn kummini ka, ki o si gbìn alikama lẹsẹ-ẹsẹ, ati barle ti a yàn, ati spelti nipò rẹ̀?