Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| IWỌ iba jẹ fà awọn ọrun ya, ki iwọ si sọkalẹ, ki awọn oke-nla ki o le yọ́ niwaju rẹ. |
| 2 |
| Gẹgẹ bi igbati iná ileru ti njo, bi iná ti imu omi hó, lati sọ orukọ rẹ di mimọ̀ fun awọn ọta rẹ, ki awọn orilẹ-ède ki o le warìri niwaju rẹ! |
| 3 |
| Nigbati iwọ ṣe nkan wọnni ti o lẹ̀ru ti awa kò fi oju sọna fun, iwọ sọkalẹ wá, awọn oke-nla yọ́ niwaju rẹ. |
| 4 |
| Nitori lati ipilẹṣẹ aiye wá, a kò ti igbọ́, bẹ̃ni eti kò ti gbọ́ ọ, bẹ̃ni oju kò ti iri Ọlọrun kan lẹhin rẹ, ti o ti pèse fun ẹniti o duro dè e. |
| 5 |
| Iwọ pade ẹniti nyọ̀ ti o nṣiṣẹ ododo, ti o ranti rẹ li ọ̀na rẹ: kiyesi i, iwọ binu; nitori awa ti dẹṣẹ̀; a si pẹ ninu wọn, a o ha si là? |
| 6 |
| Gbogbo wa si dabi ohun aimọ́, gbogbo ododo wa si dabi akisa ẹlẹgbin; gbogbo wa si rẹ̀ bi ewe; aiṣedede wa si mu wa kuro bi afẹfẹ. |
| 7 |
| Kò si ẹniti npè orukọ rẹ, ti o si rú ara rẹ̀ soke lati di ọ mu: nitori iwọ ti pa oju rẹ mọ kuro lara wa, iwọ si ti run wa, nitori aiṣedede wa. |
| 8 |
| Ṣugbọn nisisiyi, Oluwa, iwọ ni baba wa; awa ni amọ̀, iwọ si ni ọ̀mọ; gbogbo wa si ni iṣẹ ọwọ́ rẹ. |
| 9 |
| Máṣe binu kọja àla, Oluwa, ki o má si ranti aiṣedede wa titilai: kiyesi i, wò, awa bẹ̀ ọ, enia rẹ ni gbogbo wa iṣe. |
| 10 |
| Awọn ilu mimọ́ rẹ di aginju, Sioni dí aginju, Jerusalemu di ahoro. |
| 11 |
| Ile wa mimọ́ ati ologo, nibiti awọn baba wa ti nyìn ọ, li a fi iná kun: gbogbo ohun ãyo wa si ti run. |
| 12 |
| Iwọ o ha da ara rẹ duro nitori nkan wọnyi, Oluwa? iwọ o ha dakẹ, ki o si pọn wa loju kọja àla? |
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/isaiah/064.mp3
66
64