Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| Ọ̀RỌ ti o tọ̀ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa, ni wakati ti Nebukadnessari, ọba Babeli, ati gbogbo ogun rẹ̀, ati gbogbo ijọba ilẹ-ijọba ọwọ rẹ̀, ati gbogbo awọn orilẹ-ède, mba Jerusalemu ati gbogbo ilu rẹ̀ ja, wipe: |
| 2 |
| Bayi li Oluwa, Ọlọrun Israeli, wi: Lọ, ki o si sọ fun Sedekiah, ọba Juda, ki o si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi; Wò o, emi o fi ilu yi le ọwọ ọba Babeli, on o si fi iná kun u: |
| 3 |
| Iwọ kì o si le sala kuro lọwọ rẹ̀, ṣugbọn ni mimú a o mu ọ, a o si fi ọ le e lọwọ; oju rẹ yio si ri oju ọba Babeli, on o si ba ọ sọ̀rọ lojukoju, iwọ o si lọ si Babeli. |
| 4 |
| Sibẹ, gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, iwọ Sedekiah, ọba Juda: Bayi li Oluwa wi niti rẹ, Iwọ kì yio ti ipa idà kú. |
| 5 |
| Iwọ o kú li alafia: ati bi ijona-isinkú awọn baba rẹ, awọn ọba igbãni ti o wà ṣaju rẹ, bẹ̃ni nwọn o si ṣe ijona-isinkú fun ọ, nwọn o si pohunrere rẹ, pe, Yẽ oluwa! nitori eyi li ọ̀rọ ti emi ti sọ, li Oluwa wi. |
| 6 |
| Jeremiah woli, si sọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi fun Sedekiah, ọba Juda ni Jerusalemu. |
| 7 |
| Ni wakati na ogun ọba Babeli mba Jerusalemu jà, ati gbogbo ilu Juda ti o kù, Lakiṣi, ati Aseka: wọnyi li o kù ninu ilu Juda, nitori nwọn jẹ ilu olodi. |
| 8 |
| Ọ̀rọ ti o tọ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa lẹhin ti Sedekiah, ọba, ti ba gbogbo enia ti o wà ni Jerusalemu dá majẹmu, lati kede omnira fun wọn. |
| 9 |
| Pe, ki olukuluku enia le jẹ ki iranṣẹkunrin rẹ̀, ati olukuluku enia, iranṣẹbinrin rẹ̀, ti iṣe ọkunrin Heberu tabi obinrin Heberu, lọ lọfẹ; ki ẹnikẹni ki o má mu ara Juda, arakunrin rẹ̀, sìn. |
| 10 |
| Njẹ nigbati gbogbo awọn ijoye, ati gbogbo enia, ti nwọn dá majẹmu yi, gbọ́ pe ki olukuluku ki o jẹ ki iranṣẹkunrin rẹ̀, ati olukuluku, iranṣẹbinrin rẹ̀, lọ lọfẹ, ki ẹnikan má mu wọn sin wọn mọ, nwọn gbọ́, nwọn si jọ̃ wọn lọwọ. |
| 11 |
| Ṣugbọn lẹhin na nwọn yi ọkàn pada, nwọn si mu ki awọn iranṣẹkunrin ati awọn iranṣẹbinrin, awọn ẹniti nwọn ti jẹ ki o lọ lọfẹ, ki o pada, nwọn si mu wọn sin bi iranṣẹkunrin ati bi iranṣẹbinrin. |
| 12 |
| Nigbana ni ọ̀rọ Oluwa tọ Jeremiah wá lati ọdọ Oluwa, wipe, |
| 13 |
| Bayi li Oluwa Ọlọrun Israeli, wi, pe; Emi ba awọn baba nyin dá majẹmu li ọjọ ti emi mu wọn jade lati ilẹ Egipti, kuro ninu oko-ẹrú, wipe, |
| 14 |
| Li opin ọdọdun meje ki olukuluku enia jẹ ki arakunrin rẹ̀ ki o lọ, ani ara Heberu ti o ta ara rẹ̀ fun ọ; yio si sìn ọ li ọdun mẹfa, nigbana ni iwọ o jẹ ki o lọ lọfẹ lọdọ rẹ: ṣugbọn awọn baba nyin kò gbọ́ temi, bẹ̃ni wọn ko tẹti wọn silẹ. |
| 15 |
| Ẹnyin si yi ọkàn pada loni, ẹ si ti ṣe eyi ti o tọ li oju mi, ni kikede omnira, ẹnikini fun ẹnikeji rẹ̀; ẹnyin si ti dá majẹmu niwaju mi ni ile ti a fi orukọ mi pè: |
| 16 |
| Ṣugbọn ẹnyin yipada, ẹ si sọ orukọ mi di ẽri, olukuluku enia si mu ki iranṣẹkunrin rẹ̀, ati olukuluku enia iranṣẹbinrin rẹ̀, ti on ti sọ di omnira ni ifẹ wọn, ki o pada, ẹnyin si mu wọn sìn lati jẹ iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, fun nyin. |
| 17 |
| Nitorina bayi li Oluwa wi, Ẹnyin kò feti si mi, ni kikede omnira, ẹgbọ́n fun aburo rẹ̀, ati ẹnikini fun ẹnikeji rẹ̀: wò o, emi o kede omnira fun nyin, li Oluwa wi, si idà, si ajakalẹ-àrun, ati si ìyan, emi o si fi nyin fun iwọsi ni gbogbo ijọba ilẹ aiye. |
| 18 |
| Emi o si ṣe awọn ọkunrin na, ti o ti ré majẹmu mi kọja, ti kò ṣe ọ̀rọ majẹmu ti nwọn ti dá niwaju mi, bi ẹgbọrọ malu ti nwọn ti ke meji, ti nwọn si kọja lãrin ipin mejeji rẹ̀, |
| 19 |
| Awọn ijoye Juda, ati awọn ijoye Jerusalemu, awọn ìwẹfa, ati awọn alufa, ati gbogbo enia ilẹ na, ti o kọja lãrin ipin mejeji ẹgbọrọ malu na; |
| 20 |
| Emi o fi wọn le ọwọ awọn ọta wọn, ati le ọwọ awọn ti nwá ẹmi wọn: okú wọn yio si jẹ onjẹ fun awọn ẹiyẹ oju-ọrun, ati fun awọn ẹranko igbẹ. |
| 21 |
| Ati Sedekiah, ọba Juda, ati awọn ijoye rẹ̀ li emi o fi le ọwọ awọn ọta wọn, ati le ọwọ awọn ti nwá ẹmi wọn, ati le ọwọ ogun ọba Babeli, ti o ṣi lọ kuro lọdọ nyin. |
| 22 |
| Wò o, emi o paṣẹ, li Oluwa wi: emi o si mu wọn pada si ilu yi; nwọn o si ba a jà, nwọn o si kó o, nwọn o si fi iná kún u: emi o si ṣe ilu Juda li ahoro laini olugbe. |
|
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/jeremiah/034.mp3
52
34