Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| Ọ̀RỌ ti Jeremiah, woli, sọ fun Baruku, ọmọ Neriah nigbati o ti kọ ọ̀rọ wọnyi sinu iwe tan li ẹnu Jeremiah li ọdun kẹrin Jehoiakimu, ọmọ Josiah, ọba Juda, wipe, |
| 2 |
| Bayi li Oluwa, Ọlọrun Israeli, wi fun ọ, iwọ Baruku; |
| 3 |
| Iwọ wipe, Egbé ni fun mi nisisiyi! nitori ti Oluwa ti fi ibanujẹ kún ikãnu mi; ãrẹ̀ mu mi ninu ẹ̀dun mi, emi kò si ri isimi. |
| 4 |
| Bayi ni ki iwọ sọ fun u, Oluwa wi bayi; pe, Wò o, eyi ti emi ti kọ́, li emi o wo lulẹ, ati eyi ti emi ti gbìn li emi o fà tu, ani gbogbo ilẹ yi. |
| 5 |
| Iwọ ha si mbere ohun nla fun ara rẹ? máṣe bere: nitori, wò o, emi o mu ibi wá sori gbogbo ẹran-ara, li Oluwa wi: ṣugbọn ẹmi rẹ li emi o fi fun ọ bi ikogun ni gbogbo ibiti iwọ ba lọ si. |
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/jeremiah/045.mp3
52
45