|
| 1 |
|
| EMI ni ọkunrin na ti o ti ri wàhala nipa ọpa ibinu rẹ̀. |
|
| 2 |
|
| O ti fà mi, o si mu mi wá sinu òkunkun, kì si iṣe sinu imọlẹ. |
|
| 3 |
|
| Lõtọ, o yi ọwọ rẹ̀ pada si mi siwaju ati siwaju li ọjọ gbogbo. |
|
| 4 |
|
| O ti sọ ẹran-ara mi ati àwọ mi di ogbó, o ti fọ́ egungun mi. |
|
| 5 |
|
| O ti mọdi tì mi, o fi orõrò ati ãrẹ̀ yi mi ka. |
|
| 6 |
|
| O ti fi mi si ibi òkunkun, bi awọn ti o ti kú pẹ. |
|
| 7 |
|
| O ti sọgba yi mi ka, ti emi kò le jade; o ti ṣe ẹ̀wọn mi wuwo |
|
| 8 |
|
| Bi emi ti kigbe pẹlu, ti emi si npariwo, o sé adura mi mọ. |
|
| 9 |
|
| O ti fi okuta gbigbẹ sọgba yi ọ̀na mi ka, o ti yi ipa ọ̀na mi po. |
|
| 10 |
|
| On jẹ bi ẹranko beari ti o ba dè mi, bi kiniun ni ibi ìkọkọ. |
|
| 11 |
|
| O ti mu mi ṣina li ọ̀na mi, o si fà mi ya pẹrẹpẹrẹ: o ti sọ mi di ahoro. |
|
| 12 |
|
| O ti fà ọrun rẹ̀, o si fi mi ṣe itasi fun ọfa rẹ̀. |
|
| 13 |
|
| O ti mu ki ọfà apó rẹ̀ wọ inu-ẹdọ mi lọ. |
|
| 14 |
|
| Emi jẹ ẹni ẹsin fun gbogbo enia mi; orin wọn ni gbogbo ọjọ. |
|
| 15 |
|
| O ti fi ìkoro mu mi yo, o ti mu mi mu omi wahala. |
|
| 16 |
|
| O ti fi ọta ṣẹ́ ehín mi, o tẹ̀ mi mọlẹ ninu ẽru. |
|
| 17 |
|
| Iwọ si ti mu ọkàn mi jina réré si alafia; emi gbagbe rere. |
|
| 18 |
|
| Emi si wipe, Agbara mi ati ireti mi ṣègbe kuro lọdọ Oluwa. |
|
| 19 |
|
| Ranti wahala mi ati inilara mi, ani ìkoro ati orõro. |
|
| 20 |
|
| Lõtọ, nigbati ọkàn mi nṣe iranti wọn, o si tẹriba ninu mi. |
|
| 21 |
|
| Eyi ni emi o rò li ọkàn mi, nitorina emi o ma reti. |
|
| 22 |
|
| Ãnu Oluwa ni, ti awa kò parun tan, nitori irọnu-ãnu rẹ kò li opin. |
|
| 23 |
|
| Ọtun ni li orowurọ; titobi ni otitọ rẹ. |
|
| 24 |
|
| Oluwa ni ipin mi, bẹ̃li ọkàn mi wi; nitorina ni emi ṣe reti ninu rẹ̀. |
|
| 25 |
|
| Oluwa ṣe rere fun gbogbo ẹniti o duro dè e, fun ọkàn ti o ṣafẹri rẹ̀. |
|
| 26 |
|
| O dara ti a ba mã reti ni idakẹjẹ fun igbala Oluwa. |
|
| 27 |
|
| O dara fun ọkunrin, ki o gbe àjaga ni igba-ewe rẹ̀. |
|
| 28 |
|
| Ki o joko on nikan, ki o si dakẹ, nitori Ọlọrun ti gbe e le ori rẹ̀. |
|
| 29 |
|
| Ki o fi ẹnu rẹ̀ sinu ẽkuru; pe bọya ireti le wà: |
|
| 30 |
|
| Ki o fi ẹ̀rẹkẹ fun ẹniti o lù u; ki o kún fun ẹ̀gan patapata. |
|
| 31 |
|
| Nitoriti Oluwa kì yio ṣá ni tì lailai: |
|
| 32 |
|
| Bi o tilẹ mu ibanujẹ wá, sibẹ on o ni irọnu gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ̀. |
|
| 33 |
|
| Nitori on kì ifẹ ipọn-ni-loju lati ọkàn rẹ̀ wá, bẹ̃ni kì ibà ọmọ enia ninu jẹ. |
|
| 34 |
|
| Lati tẹ̀ gbogbo ara-tubu ilẹ-aiye mọlẹ li abẹ ẹsẹ rẹ̀. |
|
| 35 |
|
| Lati yi ẹ̀tọ enia sapakan niwaju Ọga-ogo julọ. |
|
| 36 |
|
| Lati yi ọ̀ran idajọ enia pada, Oluwa kò fẹ ri i? |
|
| 37 |
|
| Tali ẹniti iwi, ti isi iṣẹ, nigbati Oluwa kò paṣẹ rẹ̀. |
|
| 38 |
|
| Ibi ati rere kò ha njade lati ẹnu Ọga-ogo-julọ wá? |
|
| 39 |
|
| Ẽṣe ti enia alãye nkùn? ti o wà lãye, ki olukuluku ki o kùn nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀! |
|
| 40 |
|
| Jẹ ki a wádi, ki a si dán ọ̀na wa wò, ki a si tun yipada si Oluwa. |
|
| 41 |
|
| Jẹ ki a gbe ọkàn ati ọwọ wa soke si Ọlọrun li ọrun. |
|
| 42 |
|
| Awa ti dẹṣẹ, a si ti ṣọtẹ: iwọ kò ti dariji. |
|
| 43 |
|
| Iwọ ti fi ibinu bora, o si ṣe inunibini si wa: iwọ ti pa, o kò si ti dasi. |
|
| 44 |
|
| Iwọ ti fi awọsanma bo ara rẹ, ki adura má le là kọja. |
|
| 45 |
|
| Iwọ ti ṣe wa bi idarọ ati ohun alainilãri li ãrin awọn orilẹ-ède. |
|
| 46 |
|
| Gbogbo awọn ọta wa ti ya ẹnu wọn si wa. |
|
| 47 |
|
| Ẹ̀ru ati ọ̀fin wá sori wa, idahoro ati iparun. |
|
| 48 |
|
| Oju mi fi odò omi ṣan silẹ, nitori iparun ọmọbinrin awọn enia mi. |
|
| 49 |
|
| Oju mi dà silẹ ni omije, kò si dá, laiṣe isimi. |
|
| 50 |
|
| Titi Oluwa fi wò ilẹ, ti o wò lati ọrun wá, |
|
| 51 |
|
| Oju mi npọn ọkàn mi loju, nitori gbogbo awọn ọmọbinrin ilu mi. |
|
| 52 |
|
| Awọn ọta mi dẹkùn fun mi gidigidi, gẹgẹ bi fun ẹiyẹ laini idi. |
|
| 53 |
|
| Nwọn ti ke ẹmi mi kuro ninu iho, nwọn si yi okuta sori mi. |
|
| 54 |
|
| Nwọn mu omi ṣan lori mi; emi wipe, Mo gbe! |
|
| 55 |
|
| Emi kepe orukọ rẹ, Oluwa, lati iho jijin wá. |
|
| 56 |
|
| Iwọ ti gbọ́ ohùn mi: máṣe se eti rẹ mọ si imikanlẹ mi, si igbe mi. |
|
| 57 |
|
| Iwọ sunmọ itosi li ọjọ ti emi kigbe pè ọ: iwọ wipe: Má bẹ̀ru! |
|
| 58 |
|
| Oluwa, iwọ ti gba ijà mi jà; iwọ ti rà ẹmi mi pada. |
|
| 59 |
|
| Oluwa, iwọ ti ri inilara mi, ṣe idajọ ọran mi! |
|
| 60 |
|
| Iwọ ti ri gbogbo igbẹsan wọn, gbogbo èro buburu wọn si mi. |
|
| 61 |
|
| Iwọ ti gbọ́ ẹ̀gan wọn, Oluwa, gbogbo èro buburu wọn si mi. |
|
| 62 |
|
| Ète awọn wọnni ti o dide si mi, ati ipinnu wọn si mi ni gbogbo ọjọ. |
|
| 63 |
|
| Kiyesi ijoko wọn ati idide wọn! emi ni orin-ẹsin wọn. |
|
| 64 |
|
| San ẹsan fun wọn, Oluwa, gẹgẹ bi iṣẹ ọwọ wọn! |
|
| 65 |
|
| Fun wọn ni ifọju ọkàn, ègun rẹ lori wọn! |
|
| 66 |
|
| Fi ibinu lepa wọn, ki o si pa wọn run kuro labẹ ọrun Oluwa! |
|
|
|
|