Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| RANTI, Oluwa, ohun ti o de sori wa; rò ki o si wò ẹ̀gan wa! |
| 2 |
| A fi ogún wa le awọn alejo lọwọ, ile wa fun awọn ajeji. |
| 3 |
| Awa jẹ alaini obi, baba kò si, awọn iyá wa dabi opó. |
| 4 |
| Awa ti fi owo mu omi wa; a nta igi wa fun wa. |
| 5 |
| Awọn ti nlepa wa sunmọ ọrùn wa: ãrẹ̀ mu wa, awa kò si ni isimi. |
| 6 |
| Awa ti fi ọwọ wa fun awọn ara Egipti, ati fun ara Assiria, lati fi onjẹ tẹ́ wa lọrùn. |
| 7 |
| Awọn baba wa ti ṣẹ̀, nwọn kò si sí; awa si nrù aiṣedede wọn. |
| 8 |
| Awọn ẹrú ti jọba lori wa: ẹnikan kò si gbà wa kuro li ọwọ wọn. |
| 9 |
| Ninu ewu ẹmi wa li awa nlọ mu onjẹ wa, nitori idà ti aginju. |
| 10 |
| Àwọ wa pọ́n gẹgẹ bi àro nitori gbigbona ìyan na. |
| 11 |
| Nwọn tẹ́ awọn obinrin li ogo ni Sioni, awọn wundia ni ilu Juda. |
| 12 |
| A so awọn ijoye rọ̀ nipa ọwọ wọn: a kò buyin fun oju awọn àgbagba. |
| 13 |
| Awọn ọdọmọkunrin ru ọlọ, ãrẹ̀ mu awọn ọmọde labẹ ẹrù-igi. |
| 14 |
| Awọn àgbagba dasẹ kuro li ẹnu-bode, awọn ọdọmọkunrin kuro ninu orin wọn. |
| 15 |
| Ayọ̀ ọkàn wa ti dá; a yi ijo wa pada si ọ̀fọ. |
| 16 |
| Ade ṣubu kuro li ori wa: ègbe ni fun wa, nitori awa ti ṣẹ̀. |
| 17 |
| Nitori eyi li ọkàn wa rẹ̀wẹsi; nitori nkan wọnyi oju wa di baibai. |
| 18 |
| Nitori oke Sioni, ti dahoro, awọn kọ̀lọkọlọ nrin lori rẹ̀. |
| 19 |
| Iwọ, Oluwa, li o wà lailai; itẹ́ rẹ lati iran de iran! |
| 20 |
| Ẽṣe ti iwọ fi gbagbe wa lailai, ti o si kọ̀ wa silẹ li ọjọ pipẹ? |
| 21 |
| Oluwa, yi wa pada sọdọ rẹ, awa o si yipada; sọ ọjọ wa di ọtun gẹgẹ bi ti igbãni. |
| 22 |
| Tabi iwọ ha ti kọ̀ wa silẹ patapata, tobẹ̃ ti iwọ si binu si wa gidigidi? |
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/lamentations/005.mp3
5
5