Si wipe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; Idì nla kan, pẹlu apá nla, alapá gigùn, o kún fun iyẹ́; ti o ni àwọ alaràbarà wá si Lebanoni, o si mu ẹka igi Kedari ti o ga julọ.
O si dagba, o si di igi àjara ti o bò ti o kuru, ẹka ẹniti o tẹ̀ sọdọ rẹ̀, gbòngbo rẹ̀ si wà labẹ rẹ̀; bẹ̃ni o di ajara, o si pa ẹka, o si yọ ọ̀munú jade.
Idì nla miran si wà pẹlu apá nla ati iyẹ́ pupọ: si kiye si i, àjara yi tẹ̀ gbòngbo rẹ̀ sọdọ rẹ̀, o si yọ ẹka rẹ̀ sọdọ rẹ̀, ki o le ma b'omi si i ninu aporo ọgbà rẹ̀.
Wipe, Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; yio ha gbà? on kì yio hú gbòngbo rẹ̀, kì yio si ka eso rẹ̀ kuro, ki o le rọ? yio rọ ninu gbogbo ewe rirú rẹ̀, ani laisi agbara nla tabi enia pupọ̀ lati fà a tu pẹlu gbòngbo rẹ̀.
Sọ nisisiyi fun ọlọ̀tẹ ile na pe, Ẹnyin kò mọ̀ ohun ti nkan wọnyi jasi? Sọ fun wọn, kiyesi i, ọba Babiloni de Jerusalemu, o si ti mu ọba ibẹ ati awọn ọmọ-alade ibẹ, o si mu wọn pẹlu rẹ̀ lọ si Babiloni:
Ṣugbọn on ṣọ̀tẹ si i ni rirán awọn ikọ̀ rẹ̀ lọ si Egipti, ki nwọn ki o le fi ẹṣin fun u ati enia pupọ. Yio ha sàn a? ẹniti nṣe iru nkan wọnyi yio ha bọ́? tabi yio dalẹ tan ki o si bọ́?
Oluwa Ọlọrun wipe, Bi mo ti wà, nitotọ ibi ti ọba ngbe ti o fi i jọba, ibura ẹniti o gàn, majẹmu ẹniti o si bajẹ, ani lọdọ rẹ̀ lãrin Babiloni ni yio kú.
Bẹ̃ni Farao ti on ti ogun rẹ̀ ti o li agbara ati ẹgbẹ́ nla kì yio ṣe fun u ninu ogun, nipa mimọ odi, ati kikọle iṣọ́ ti o li agbara, lati ke enia pupọ̀ kuro:
Ati gbogbo awọn isánsa rẹ̀ pẹlu gbogbo awọn ẹgbẹ́-ogun rẹ̀, ni yio ti oju idà ṣubu; awọn ti o si kù ni a o tuka si gbogbo ẹfũfu: ẹnyin o si mọ̀ pe emi Oluwa li o ti sọ ọ.
Bayi ni Oluwa Ọlọrun wi; emi o mu ninu ẹka ti o ga jùlọ, ninu igi Kedari giga; emi o si lọ́ ọ, emi o ke ọ̀munú ẹka kan kuro ninu ọ̀munú ẹka rẹ̀; emi o si gbìn i sori oke giga kan ti o si hàn:
Lori oke giga ti Israeli ni emi o gbìn i si, yio si yọ ẹka; yio si so eso, yio si jẹ igi Kedari daradara; labẹ rẹ̀ ni gbogbo ẹiyẹ oniruru iyẹ́ o si gbe; ninu ojiji ẹka rẹ̀ ni nwọn o gbe.
Gbogbo igi inu igbẹ ni yio si mọ̀ pe, emi Oluwa li o ti mu igi giga walẹ, ti mo ti gbe igi rirẹlẹ soke, ti mo ti mu igi tutù gbẹ, ti mo si ti mu igi gbigbẹ ruwé: emi Oluwa li o ti sọ ti mo si ti ṣe e.