Nitorina, iwọ wipe, Bayi li Oluwa Ọlọrun wi, Ilu ti o ta ẹjẹ silẹ lãrin rẹ̀, ki akoko rẹ̀ ki o le de, o si ṣe oriṣa si ara rẹ̀ lati sọ ara rẹ̀ di aimọ́.
Iwọ ti di ẹlẹbi niti ẹjẹ rẹ ti iwọ ti ta silẹ; iwọ si ti sọ ara rẹ di aimọ́ niti òriṣa rẹ ti iwọ ti ṣe, iwọ si ti mu ọjọ rẹ summọ tosí, iwọ si ti dé ọdun rẹ: nitorina ni mo ṣe sọ ọ di ẹgàn si awọn keferi, ati ẹsín si gbogbo ilẹ.
Ẹnikan si ti ṣe ohun irira pẹlu aya aladugbo rẹ̀: ẹlomiran si ti fi ifẹkufẹ bà aya-ọmọ rẹ̀ jẹ́; ẹlomiran ninu rẹ si ti tẹ́ arabinrin rẹ̀ logo, ọmọ baba rẹ̀.
Ninu rẹ ni nwọn ti gba ẹbùn lati ta ẹjẹ silẹ: iwọ ti gba ẹdá ati elé, o si ti fi iwọra jère lara awọn aladugbo rẹ, nipa ilọni lọwọ-gbà; o si ti gbagbe mi, ni Oluwa, Ọlọrun wi.
Gẹgẹ bi nwọn ti ima ko fadaka, ati idẹ, ati irin, ati ojé, ati tánganran jọ si ãrin ileru, lati fin iná si i, ki a lè yọ́ ọ, bẹ̃ni emi o kó nyin ni ibinu mi, ati irúnu mi, emi o si fi nyin sibẹ emi o yọ́ nyin.
Ìditẹ awọn wolĩ rẹ̀ wà lãrin rẹ̀, bi kiniun ti nke ramuramu ti nṣọdẹ; nwọn ti jẹ ọkàn run, nwọn ti kó ohun iṣura ati ohun iyebiye; nwọn ti sọ ọ̀pọlọpọ di opó fun u lãrin rẹ̀.
Awọn alufa rẹ̀ ti rú ofin mi, nwọn si fi sọ ohun mimọ́ mi di àilọwọ: nwọn kò fi ìyatọ sãrin ohun mimọ́ ati àilọwọ, bẹ̃ni nwọn kò fi ìyatọ hàn lãrin ohun aimọ́, ati mimọ́, nwọn si ti fi oju wọn pamọ kuro li ọjọ isimi mi, mo si di ẹmi àilọwọ lãrin wọn.