LI ọdun kẹ̃dọgbọn oko-ẹrú wa, ni ibẹ̀rẹ ọdun na, li ọjọ ikẹwa oṣù, li ọdun ikẹrinla lẹhin igbati ilu fọ́, li ọjọ na gan, ọwọ́ Oluwa wà lara mi, o si mu mi wá sibẹ na.
Ọkunrin na si wi fun mi pe, Ọmọ enia, fi oju rẹ wò, ki o si fi eti rẹ gbọ́, ki o si gbe ọkàn rẹ le ohun gbogbo ti emi o fi han ọ; nitori ka ba le fi wọn han ọ li a ṣe mu ọ wá ihinyi: sọ ohun gbogbo ti o ri fun ile Israeli.
Si kiye si i, ogiri kan mbẹ lode ile na yika, ije iwọ̀nlẹ kan si mbẹ lọwọ ọkunrin na, igbọnwọ mẹfa, nipa igbọnwọ ati ibú atẹlẹwọ kan: o si wọ̀n ibú ile na, ije kan; ati giga rẹ̀, ije kan.
Nigbana li o wá si ẹnu-ọ̀na ti o kọju si ọ̀na ila-õrun, o si gùn oke atẹ̀gun na lọ, o si wọ̀n iloro ẹnu ọ̀na, ti o jẹ ije kan ni ibú; ati iloro miran ti ẹnu-ọ̀na na, ti o jẹ ije kan ni ibú.
Ati yará kékèké ẹnu-ọ̀na ti ọ̀na ila-õrun jẹ mẹta nihà ìhin, ati mẹta nihà ọhún; awọn mẹtẹta jẹ ìwọn kanna: awọn atẹrigba na jẹ ìwọn kanna niha ìhin ati niha ọhún.
Àye ti si mbẹ niwaju awọn yará kékèké na jẹ igbọnwọ kan nihà ìhin, àye na si jẹ igbọnwọ kan nihá ọhún; awọn yará kékèké na si jẹ igbọnwọ mẹfa nihà ìhin, ati igbọnwọ mẹfa niha ọhún.
Awọn ferese tõro si mbẹ lara yará kékèké na, ati lara atẹrigba wọn ninu ẹnu-ọ̀na niha gbogbo ati pẹlu yará iloro: ferese pupọ si mbẹ niha inu gbogbo: igi ọpẹ si mbẹ lara olukuluku atẹrigbà.
Ati fèrese wọn, ati iloro wọn, ati igi ọpẹ wọn jẹ gẹgẹ bi ìwọn ti ẹnu-ọ̀na ti o kọju si ọ̀na ila-õrun; nwọn si ba atẹgun meje gùn oke rẹ̀ lọ; awọn iloro na si mbẹ niwaju wọn.
Atẹ̀gun meje ni mbẹ lati bá gùn oke rẹ̀, ati awọn iloro rẹ̀ si mbẹ niwaju wọn: o si ni igi ọpẹ, ọkan nihà ìhin, ati ọkan nihà ọhún, lara awọn atẹrigbà rẹ̀.
Ati awọn yará kékèké rẹ̀, ati atẹrigbà rẹ̀, ati iloro rẹ̀, gẹgẹ bi ìwọn wọnyi: ferese pupọ̀ si mbẹ nibẹ ati ni iloro rẹ̀ yika: o jẹ ãdọta igbọnwọ ni gigùn, igbọnwọ mẹ̃dọgbọn ni ibú.
Ati yara kékèké rẹ̀, ati atẹrigbà rẹ̀, ati iloro rẹ̀, jẹ gẹgẹ bi ìwọn wọnyi: ferese si mbẹ ninu rẹ̀ ati ninu awọn iloro rẹ̀ yika: o jẹ ãdọta igbọnwọ ni gigùn, ati igbọnwọ mẹ̃dọgbọn ni ibú.
Ati ni iloro ẹnu-ọ̀na na tabili meji mbẹ nihà ìhin, ati tabili meji nihà ọ̀hun, lati ma pa ẹran ẹbọ sisun, ati ọrẹ ẹbọ ẹ̀ṣẹ, ati ọrẹ ẹbọ irekọja lori wọn.
Tabili mẹrin na si jẹ ti okuta gbigbẹ́ fun ọrẹ ẹbọ sisun, igbọnwọ kan on ãbọ ni gigùn, ati igbọnwọ kan on ãbọ ni ibú, ati igbọnwọ kan ni giga: lori eyiti nwọn a si ma kó ohun-elò wọn le, ti nwọn ifi pa ọrẹ ẹbọ sisun ati ẹran ẹbọ.
Ati lode ẹnu-ọ̀na ti inu ni yará awọn akọrin gbe wà, ninu agbala ti inu, ti mbẹ ni ihà ẹnu-ọ̀na ariwa; oju wọn si wà li ọ̀na gusu: ọkan ni iha ẹnu-ọ̀na ila-õrun, oju eyiti mbẹ li ọ̀na ariwa.
Yará ti oju rẹ̀ mbẹ li ọ̀na ariwa, ni fun awọn alufa, awọn olutọjú iṣọ pẹpẹ na; awọn wọnyi li awọn ọmọ Sadoku ninu awọn ọmọ Lefi, ti nwọn ima sunmọ Oluwa lati ṣe iranṣẹ fun u.
O si mu mi wá si iloro ile na, o si wọ̀n opo iloro na, igbọnwọ marun nihà ìhin, ati igbọnwọ marun nihà ọ̀hun: ibu ẹnu-ọ̀na na si jẹ igbọnwọ mẹta nihà ìhin, ati igbọnwọ mẹta nihà ọ̀hun.
Gigùn iloro na jẹ ogún igbọnwọ, ibú rẹ̀ igbọnwọ mọkànla; o si mu mi wá si atẹ̀gun ti nwọn ifi ba gokè rẹ̀: ọwọ̀n pupọ̀ si mbẹ nihà ibi atẹrigbà, ọkan nihin, ati ọkan lọhun.