Ati ibú ilẹkùn na jẹ igbọnwọ mẹwa; ihà ilẹkùn na si jẹ igbọnwọ marun li apakan, ati igbọnwọ marun li apakeji; o si wọ̀n gigùn rẹ̀, ogoji igbọnwọ; ati ibú rẹ̀, ogún igbọnwọ.
Ati awọn yará-ihà, ọkan lori ekeji jẹ mẹta, nigba ọgbọ̀n: nwọn si wọ̀ inu ogiri ti ile awọn yará-ihà na yika, ki nwọn ba le di ara wọn mu, nitori kò si idimú ninu ogiri ile na.
A si ṣe e gborò, o si lọ yika loke awọn yará ihà: nitori ogiri ile na lọ loke-loke yi ile na ka: nitorina ibú ile na wà loke, bẹ̃ni iyará isalẹ yọ si toke lãrin.
Ati ilẹkùn awọn yará-ẹ̀gbẹ́ na mbẹ li ọ̀na ibi ti o kù, ilẹkùn kan li ọ̀na ariwa, ati ilẹkùn kan ni gusu: ati ibú ibẹ̀ na ti o kù, jẹ igbọnwọ marun yika.
Ati ile ti o wà niwaju eyiti a yà sọtọ̀ ni igun ọ̀na iwọ-õrun, jẹ ãdọrin igbọnwọ ni gbigborò; ogiri ile na si jẹ igbọnwọ marun ni ibú yika, ati gigùn rẹ̀, ãdọrun igbọnwọ.
O si wọ̀n gigun ile na ti o kọju si ibiti a yà sọtọ̀ ti mbẹ lẹhin rẹ̀, ati ibujoko-oke ni ihà kan ati nihà miran, ọgọrún igbọnwọ, pẹlu tempeli inu, ati iloro agbalá na;
Awọn iloro, ati ferese toro, ati ibujoko oke yika lori ile olorule mẹta wọn, ti o wà niwaju iloro na, li a fi igi tẹ́ yika, ati lati ilẹ de oke ferese, a si bò awọn ferese na;
Pẹpẹ igi na jẹ igbọnwọ mẹta ni giga, gigùn rẹ̀ igbọnwọ meji; ati igun rẹ̀, ati gigùn rẹ̀, ati awọn ogiri rẹ̀ jẹ ti igi: o si wi fun mi pe, Eyi ni tabili ti mbẹ niwaju Oluwa.