BAYI li Oluwa Ọlọrun wi; Ẹnu-ọ̀na agbala ti inu ti o kọju si ila-õrun yio wà ni titì ni ọjọ mẹfa ti a fi iṣiṣẹ; ṣugbọn ni ọjọ isimi li a o ṣi i silẹ, ati li ọjọ oṣù titun li a o si ṣi i silẹ.
Olori na yio si ba ẹnu-ọ̀na iloro ti ẹnu-ọ̀na ode wọle, yio si duro nibi opó ẹnu-ọ̀na, awọn alufa yio si pèse ọrẹ ẹbọ sisun rẹ̀ ati ọrẹ ẹbọ idupẹ rẹ̀, on o si ma sìn ni iloro ẹnu-ọ̀na: yio si jade wá; a kì yio si tì ẹnu-ọ̀na titi di aṣalẹ.
Yio si pèse ọrẹ-ẹbọ jijẹ, efa fun ẹgbọ̀rọ akọ malu kan, ati efa kan fun agbò kan, ati fun awọn ọdọ-agutan gẹgẹ bi ọwọ́ rẹ̀ ba ti to, ati hini ororo kan fun efa kan.
Nigbati enia ilẹ na yio ba si wá siwaju Oluwa ni awọn apejọ ọ̀wọ, ẹniti o ba ba ọ̀na ẹnu-ọ̀na ariwa wọle lati sìn, yio ba ọ̀na ẹnu-ọ̀na gusu jade; ẹniti o ba si ba ọ̀na ẹnu-ọ̀na gusu wọle yio si ba ọ̀na ẹnu-ọ̀na ariwa jade; kì yio ba ọ̀na ẹnu-ọ̀na ti o ba wọle jade, ṣugbọn yio jade lodi keji.
Ati ninu awọn asè ati ninu awọn ajọ, ọrẹ-ẹbọ jijẹ yio jẹ efa kan fun ẹgbọ̀rọ akọ-malu kan, ati efa kan fun agbò kan, ati fun awọn ọdọ-agutan ẹbùn ọwọ́ rẹ̀, ati hini ororo kan fun efa kan.
Nigbati olori na yio ba si pèse ọrẹ-ẹbọ sisun atinuwá, tabi ọrẹ-ẹbọ idupẹ atinuwá fun Oluwa, ẹnikan yio si ṣi ilẹkun ti o kọjusi ila-õrun fun u, yio si pèse ọrẹ-ẹbọ sisun rẹ̀, ati ẹbọ idupẹ rẹ̀, bi o ti ṣe li ọjọ-isimi: yio si jade; ati lẹhin ijadelọ rẹ̀ ẹnikan yio tì ilẹkun.
Iwọ o si pèse ọrẹ-ẹbọ jijẹ fun u lorowurọ̀, idamẹfa efa, ati idamẹfa hini ororo kan, lati fi pò iyẹfun daradara na; ọrẹ-ẹbọ jijẹ nigbagbogbo nipa aṣẹ lailai fun Oluwa.
Bi o ba si fi ẹbùn ninu ini rẹ̀ fun ọkan ninu awọn iranṣẹ rẹ̀, nigbana yio jẹ tirẹ̀ titi di ọdun omnira; yio si tun pada di ti olori na: ṣugbọn ogún rẹ̀ yio jẹ ti awọn ọmọ rẹ̀ fun wọn.
Olori na kì yio si fi ipá mu ninu ogún awọn enia lati le wọn jade kuro ninu ini wọn, yio fi ogún fun awọn ọmọ rẹ̀ lara ini ti ontikalarẹ̀: ki awọn enia mi ki o má ba tuká, olukuluku kuro ni ini rẹ̀.
O si mu mi kọja li abawọ̀, ti o wà lẹba ẹnu-ọ̀na, si awọn yará mimọ́ ti awọn alufa, ti o kọjusi ariwa: si kiyesi i, ibi kan wà nibẹ̀ ni ihà mejeji iwọ-õrun.
O si wi fun mi pe, Eyi ni ibiti awọn alufa yio ma sè ọrẹ irekọja ati ọrẹ ẹ̀ṣẹ, nibiti nwọn o ma yan ọrẹ jijẹ; ki nwọn má ba gbe wọn jade si agbalá ode, lati sọ awọn enia di mimọ́.