“Ẹ bá ìyáa yín wí, ẹ bá a wí, nítorí pé kì í ṣe ìyàwó mi, Èmi náà kì í sì í ṣe ọkọ rẹ̀. Jẹ́ kí ó yọ àgbèrè rẹ̀ kúrò lójú rẹ̀ àti àìsòótọ́ kúrò ní àyà rẹ̀.
Àìṣe bẹ́ẹ̀ èmi yóò tú u sí ìhòòhò Èmi yóò sì gbé e kalẹ̀ lá ìwọṣọ gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ tí a bí i. Èmi yóò ṣe ọ́ bí i aṣálẹ̀ ilẹ̀, Èmi yóò sì sọ ọ́ di ìyàngbẹ ilẹ̀ Èmi yóò sì fi òùngbẹ gbẹ ẹ́.
Ìyá wọn jẹ́ aláìsòótọ́ ó sì lóyún wọn nínú ìtìjú. Ó wí pé, ‘èmi ó tún tọ́ àwọn àyànfẹ́ mi, tó ń fún mi ní oúnjẹ àti omi, aṣọ oríṣìíríṣìí, òróró àti ohun mímu’ lẹ́yìn.
Yóò sáré lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ ṣùgbọ́n kò ní bá wọn; Yóò wá wọn ṣùgbọ́n kò ní rí wọn. Nígbà náà ni yóò sọ pé, ‘Èmi ó padà sí ọ̀dọ̀ ọkọ mi àkọ́kọ́ nítorí pé ó dára fún mi nígbà náà ju ìsinsìnyí lọ.’
Nítorí pé kò tí ì mọ̀ pé èmi ni àti ẹni tó fún un ní ọkà, ọtí-wáìnì tuntun àti òróró ẹni tí ó fún un ní fàdákà àti wúrà lọ́pọ̀lọpọ̀ Èyí tí wọ́n lò fún Báálì
“Nítorí náà, èmi yóò mú ọkà mi kúrò nígbà tó bá pọ́n, èmi yóò sì mú wáìnì mi kúrò ní àsìkò rẹ̀. Èmi yóò sì gba ìrun àgùntàn irun àgùtàn àti ọ̀gbọ̀ mi padà mo ti fifun un láti bo ìhòòho rẹ̀.
Èmi yóò pa àjàrà àti igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀ run, Èyí tí ó pè ní èrèe rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn Olólùfẹ́ rẹ̀, Èmi yóò sọ wọ́n di igbó, àwọn ẹranko búburú yóò sì jẹ́ wọn run.
Èmi yóò jẹ́ ẹ́ níyà fún gbogbo ọjọ́ tó fi jo tùràrí sí Báálì tí ó fi òrùka àti ohun ọ̀ṣọ́ wọ ara rẹ̀ tán, tó sì tẹ̀lé àwọn olólùfẹ́ rẹ̀ lọ. Ṣùgbọ́n ó gbàgbé èmi,” ni OLÚWA wí.
Níbẹ̀ ni èmi yóò ti dá ọgbà àjàrà rẹ̀ padà fún un, Èmi yóò fi àfonífojì Ákórì ṣe ilẹ̀kùn ìrètí fún un. Yóò sì kọrin níbẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà èwe rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìgbà tó kúrò ní Éjíbítì
Ní ọjọ́ náà, èmi yóò ṣe májẹ̀mú fún wọn àti àwọn ẹranko ìgbẹ́ àti ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹ̀dá tí ń rìn lórí ilẹ̀. Kí wọn má bà á bẹ̀rù ara wọn mọ́ Ọrun, idà àti ogun jíjà ni èmi ó parun ní ilẹ̀ náà kí gbogbo ènìyàn bá a lè wà ní àìléwu.
Èmi ó sì gbìn-ín fún ara mi lórí ilẹ̀ náà Èmi yóò ṣàánú fún ẹni tí kò tì í ri ‘àànú Gbà.’ Èmi yóò sọ fún àwọn tí ‘Kì í ṣe ènìyàn mi pé,’ ‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi’; àwọn náà yóò sì wí pé, ‘Ìwọ ni Ọlọ́run mi.’ ”