Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| Ẹ wá, ẹ jẹ ki a yipadà si Oluwa: nitori o ti fà wa ya, on o si mu wa lara da; o ti lù wa, yio si tun wa dì. |
| 2 |
| Lẹhìn ijọ meji, yio tún wa jí: ni ijọ kẹta yio ji wa dide, awa o si wà lãyè niwaju rẹ̀. |
| 3 |
| Nigbana li awa o mọ̀, bi a ba tẹramọ́ ati mọ̀ Oluwa: ati pèse ijadelọ rẹ̀ bi owùrọ: on o si tọ̀ wa wá bi ojò: bi arọ̀kuro ati akọrọ̀ òjo si ilẹ. |
| 4 |
| Efraimu, kili emi o ṣe si ọ? Juda, kili emi o ṣe si ọ? nitori ore nyin dàbi ikuku owurọ̀, ati bi ìri kùtukùtu ti o kọja lọ. |
| 5 |
| Nitorina ni mo ṣe fi ãké ké wọn lati ọwọ awọn woli; mo ti fi ọ̀rọ ẹnu mi pa wọn: ki idajọ rẹ le ri bi imọlẹ ti o jade lọ. |
| 6 |
| Nitori ãnu ni mo fẹ́, ki iṣe ẹbọ; ati ìmọ Ọlọrun jù ọrẹ-ẹbọ sisun lọ. |
| 7 |
| Ṣugbọn bi Adamu nwọn ti dá majẹmu kọja: nibẹ̀ ni nwọn ti ṣẹ̀tan si mi. |
| 8 |
| Gileadi ni ilu awọn ti nṣiṣẹ ẹ̀ṣẹ, a si ti fi ẹ̀jẹ bà a jẹ. |
| 9 |
| Ati gẹgẹ bi ọwọ́ olè iti lùmọ dè enia, bẹ̃ni ẹgbẹ́ awọn alufa fohùnṣọ̀kan lati pania li ọ̀na: nitori nwọn dá ẹ̀ṣẹ nla. |
| 10 |
| Mo ti ri ohun buburu kan ni ile Israeli: agbère Efraimu wà nibẹ̀, Israeli ti bajẹ. |
| 11 |
| Iwọ Juda pẹlu, on ti gbe ikorè kalẹ fun ọ, nigbati mo ba yi igbekun awọn enia mi padà. |
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/hosea/006.mp3
14
6