Emi o kó gbogbo orilẹ-ède jọ pẹlu, emi o si mu wọn wá si afonifojì Jehoṣafati, emi o si ba wọn wijọ nibẹ̀ nitori awọn enia mi, ati nitori Israeli iní mi, ti nwọn ti fọ́n ka sãrin awọn orilẹ̀-ede, nwọn si ti pín ilẹ mi.
Nwọn si ti di ibò fun awọn enia mi; nwọn si ti fi ọmọdekunrin kan fun panṣagà obinrin kan, nwọn si ti tà ọmọdebinrin kan fun ọti-waini, ki nwọn ki o le mu.
Nitõtọ, ati ki li ẹnyin ni ifi mi ṣe, ẹnyin Tire ati Sidoni, ati gbogbo ẹkùn Palestina? ẹnyin o ha san ẹsan fun mi? bi ẹnyin ba si san ẹsan fun mi, ni kánkan ati ni koyákoyá li emi o san ẹsan nyin padà sori ara nyin.
Emi o si tà awọn ọmọkunrin nyin ati awọn ọmọbinrin nyin si ọwọ́ awọn ọmọ Juda, nwọn o si tà wọn fun awọn ara Sabia, fun orilẹ-ède kan ti o jinà rére, nitori Oluwa li o ti sọ ọ.
Oluwa yio si ké ramùramù lati Sioni wá, yio si fọ ohùn rẹ̀ jade lati Jerusalemu wá; awọn ọrun ati aiye yio si mì: ṣugbọn Oluwa yio ṣe ãbò awọn enia rẹ̀, ati agbara awọn ọmọ Israeli.
Yio si ṣe li ọjọ na, awọn oke-nla yio ma kán ọti-waini titún silẹ, awọn oke kékèké yio ma ṣàn fun warà, ati gbogbo odò Juda yio ma ṣan fun omi, orisun kan yio si jade lati inu ile Oluwa wá, yio si rin afonifojì Ṣittimu.