Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| OLUWA si sọ fun Mose pe, |
| 2 |
| Sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Bi obinrin kan ba lóyun, ti o si bi ọmọkunrin, nigbana ni ki o jẹ́ alaimọ́ ni ijọ́ meje; gẹgẹ bi ọjọ́ ìyasọtọ fun ailera rẹ̀ ni ki o jẹ́ alaimọ́. |
| 3 |
| Ni ijọ́ kẹjọ ni ki a si kọ ọmọkunrin na nilà. |
| 4 |
| Ki obinrin na ki o si wà ninu ẹ̀jẹ ìwẹnumọ́ rẹ̀ li ọjọ́ mẹtalelọgbọ̀n; ki o máṣe fọwọkàn ohun mimọ́ kan, bẹ̃ni ki o máṣe lọ sinu ibi mimọ́, titi ọjọ́ ìwẹnumọ́ rẹ̀ yio fi pé. |
| 5 |
| Ṣugbọn bi o ba bi ọmọbinrin, nigbana ni ki o jẹ́ alaimọ́ li ọsẹ̀ meji, bi ti inu ìyasọtọ rẹ̀: ki o si wà ninu ẹ̀jẹ ìwẹnumọ́ rẹ̀ li ọgọta ọjọ́ o le mẹfa. |
| 6 |
| Nigbati ọjọ́ ìwẹnumọ́ rẹ̀ ba pé, fun ọmọkunrin, tabi fun ọmọbinrin, ki o mú ọdọ-agutan ọlọdún kan wá fun ẹbọ sisun, ati ẹiyẹle, tabi àdaba, fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ tọ̀ alufa wá, si ẹnu-ọ̀na agọ ajọ: |
| 7 |
| Ẹniti yio ru u niwaju OLUWA, ti yio si ṣètutu fun u; on o si di mimọ́ kuro ninu isun ẹ̀jẹ rẹ̀. Eyi li ofin fun ẹniti o bi ọmọkunrin tabi ọmọbinrin. |
| 8 |
| Bi kò ba si le mú ọdọ-agutan wá, njẹ ki o mú àdaba meji, tabi ọmọ ẹiyẹle meji wá; ọkan fun ẹbọ sisun, ati ekeji fun ẹbọ ẹ̀ṣẹ: alufa yio si ṣètutu fun u, on o si di mimọ́. |
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/leviticus/012.mp3
27
12