Ki nwọn ki o si jasi mimọ́ fun Ọlọrun wọn, ki nwọn ki o má si ṣe bà orukọ Ọlọrun wọn jẹ́: nitoripe ẹbọ OLUWA ti a fi ina ṣe, ati àkara Ọlọrun wọn, ni nwọn fi nrubọ: nitorina ni ki nwọn ki o jẹ́ mimọ́.
Nwọn kò gbọdọ fẹ́ aya ti iṣe àgbere, tabi ẹni ibàjẹ́; bẹ̃ni nwọn kò gbọdọ fẹ́ obinrin ti a ti ọdọ ọkọ rẹ̀ kọ̀silẹ: nitoripe mimọ́ li on fun Ọlọrun rẹ̀.
Ati olori alufa ninu awọn arakunrin rẹ̀, ori ẹniti a dà oróro itasori si, ti a si yàsọtọ lati ma wọ̀ aṣọ wọnni, ki o máṣe ṣi ibori rẹ̀, tabi ki o fà aṣọ rẹ̀ ya;
Bẹ̃ni ki o máṣe jade kuro ninu ibi mimọ́, bẹ̃ni ki o máṣe bà ibi mimọ́ Ọlọrun rẹ̀ jẹ́, nitoripe adé oróro itasori Ọlọrun rẹ̀ mbẹ lori rẹ̀: Emi li OLUWA.
Ẹnikẹni ti o ní àbuku ninu irúọmọ Aaroni alufa kò gbọdọ sunmọtosi lati ru ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe: on li àbuku; kò gbọdọ sunmọtosi lati rubọ àkara Ọlọrun rẹ̀.
Kìki on ki yio wọ̀ inu aṣọ-ikele nì lọ, bẹ̃ni ki o máṣe sunmọ pẹpẹ, nitoriti on ní àbuku; ki on ki o máṣe bà ibi mimọ́ mi jẹ́: nitori Emi li OLUWA ti o yà wọn simimọ́.