Bi o ba si ṣepe lati ọmọ oṣù kan lọ titi di ọmọ ọdún marun, njẹ ki idiyelé rẹ fun ọkunrin ki o jẹ́ ṣekeli fadakà marun, ati fun obinrin, idiyelé rẹ yio jẹ ṣekeli fadakà mẹta.
Ṣugbọn bi on ba ṣe talakà jù idiyele lọ, njẹ ki o lọ siwaju alufa, ki alufa ki o diyelé e; gẹgẹ bi agbara ẹniti o jẹ́ ẹjẹ́ na ni ki alufa ki o diyelé e.
On kò gbọdọ pa a dà, bẹ̃ni kò gbọdọ pàrọ rẹ̀, rere fun buburu, tabi buburu fun rere: bi o ba ṣepe yio pàrọ rẹ̀ rára, ẹran fun ẹran, njẹ on ati ipàrọ rẹ̀ yio si jẹ́ mimọ́.
Bi enia kan yio ba si yà ile rẹ̀ sọtọ̀ lati jẹ́ mimọ́ fun OLUWA, njẹ ki alufa ki o diyelé e, ibaṣe rere tabi buburu: bi alufa ba ti diyelé e, bẹ̃ni ki o ri.
Bi enia kan ba si nfẹ́ yà ninu oko ti o jogún sọ̀tọ fun OLUWA, njẹ ki idiyelé rẹ ki o jẹ́ bi irugbìn rẹ̀: òṣuwọn homeri irugbìn barle kan ãdọta ṣekeli fadakà.
Ṣugbọn bi o ba yà oko rẹ̀ sọtọ̀ lẹhin ọdún jubeli, njẹ ki alufa ki o ṣìro owo rẹ̀ fun u, gẹgẹ bi ìwọn ọdún ti o kù, titi di ọdún jubeli, a o si din i kù ninu idiyelé rẹ.
Bi o ba ṣe ti ẹran alaimọ́ ni, njẹ ki o gbà a silẹ gẹgẹ bi idiyelé rẹ, ki o si fi idamarun rẹ̀ kún u: tabi bi kò ba si rà a pada, njẹ ki a tà a, gẹgẹ bi idiyelé rẹ.
Ṣugbọn kò sí ohun ìyasọtọ kan, ti enia ba yàsọtọ fun OLUWA ninu ohun gbogbo ti o ní, ati enia, ati ẹran, ati ilẹ-iní rẹ̀, ti a gbọdọ tà tabi ti a gbọdọ rà pada: ohun gbogbo ti a ba yàsọtọ mimọ́ julọ ni si OLUWA.
Ki o máṣe yẹ̀ ẹ wò bi o jẹ́ rere tabi buburu, bẹ̃li on kò gbọdọ pàrọ rẹ̀: bi o ba si ṣepe o pàrọ rẹ̀ rára, njẹ ati on ati ipàrọ rẹ̀ yio jẹ́ mimọ́; a kò gbọdọ rà a pada.