Ṣugbọn ẹ máṣe wá Beteli, bẹ̃ni ki ẹ má wọ̀ inu Gilgali lọ, ẹ má si rekọja lọ si Beerṣeba: nitori lõtọ Gilgali yio lọ si igbèkun, Beteli yio si di asan.
Ẹ wá ẹniti o dá irawọ̀ meje nì ati Orioni, ti o si sọ ojiji ikú di owurọ̀, ti o si fi oru mu ọjọ ṣokùnkun: ti o pè awọn omi okun, ti o si tú wọn jade soju aiye: Oluwa li orukọ rẹ̀:
Nitorina niwọ̀n bi itẹ̀mọlẹ nyin ti wà lori talakà, ti ẹnyin si gba ẹrù alikama lọwọ rẹ̀: ẹnyin ti fi okuta ti a gbẹ́ kọ́ ile, ṣugbọn ẹ kì o gbe inu wọn; ẹnyin ti gbìn ọgbà àjara daradara, ṣugbọn ẹ kì o mu ọti-waini wọn.
Nitori mo mọ̀ onirũru irekọja nyin, ati ẹ̀ṣẹ nla nyin: nwọn npọ́n olododo loju, nwọn ngbà owo abẹ̀tẹlẹ, nwọn si nyi awọn talakà si apakan ni bodè, kuro ninu are wọn.
Nitorina Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun, ani Oluwa wi bayi pe, Ẹkun yio wà ni gbogbo ita; nwọn o si ma wi ni gbogbo òpopó ọ̀na pe, Ã! ã! nwọn o si pè agbẹ̀ si iṣọ̀fọ, ati iru awọn ti o gbọ́n lati pohùnrére si isọkún.