OLUWA, ṣé àwọn odò ni inú rẹ ń ru sí ni, àbí àwọn ìṣàn omi ni ò ń bínú sí, tabi òkun ni ò ń bá bínú, nígbà tí o bá gun àwọn ẹṣin rẹ, tí o wà ninu kẹ̀kẹ́ ogun rẹ?
Mo gbọ́, àyà mi sì lù kìkì, ètè mi gbọ̀n pẹ̀pẹ̀ nígbà tí mo gbọ́ ìró rẹ̀; egungun mi bẹ̀rẹ̀ sí rà, ẹsẹ̀ mi ń gbọ̀n rìrì nílẹ̀. N óo fi sùúrù dúró jẹ́ẹ́ de ọjọ́ tí ìṣòro yóo dé bá àwọn tí wọ́n kó wa lẹ́rù.
Bí igi ọ̀pọ̀tọ́ kò tilẹ̀ rúwé, tí àjàrà kò sì so, tí kò sí èso lórí igi olifi; tí àwọn irúgbìn kò sì so lóko, tí àwọn agbo aguntan run, tí kò sì sí mààlúù ninu agbo mọ́,
Ọlọrun, OLUWA, ni agbára mi; Ó mú kí ẹsẹ̀ mi yá nílẹ̀ bíi ti àgbọ̀nrín, ó mú mi rìn lórí àwọn òkè gíga. (Sí ọ̀gá akọrin; pẹlu àwọn ohun èlò orin olókùn.)