Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| LI ọjọ na isun kan yio ṣi silẹ fun ile Dafidi ati fun awọn ara Jerusalemu, fun ẹ̀ṣẹ ati fun ìwa aimọ́. |
| 2 |
| Yio si ṣe li ọjọ na, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi, li emi o ke orukọ awọn òriṣa kuro ni ilẹ na, a kì yio si ranti wọn mọ: ati pẹlu emi o mu awọn woli ati awọn ẹmi aimọ́ kọja kuro ni ilẹ na. |
| 3 |
| Yio si ṣe, nigbati ẹnikan yio sọtẹlẹ sibẹ̀, ni baba rẹ̀ ati iya rẹ̀ ti o bi i yio wi fun u pe, Iwọ kì yio yè: nitori iwọ nsọ̀rọ eké li orukọ Oluwa: ati baba rẹ̀ ati iya rẹ̀ ti o bi i yio gún u li agúnyọ nigbati o ba sọ̀tẹlẹ. |
| 4 |
| Yio si ṣe li ọjọ na, oju yio tì awọn woli olukulukù nitori iran rẹ̀, nigbati on ba ti sọtẹlẹ; bẹ̃ni nwọn kì yio si wọ̀ aṣọ onirun lati tan ni jẹ: |
| 5 |
| Ṣugbọn on o wipe, Emi kì iṣe woli, agbẹ̀ li emi; nitori enia li o ni mi bi iranṣẹ lati igbà ewe mi wá. |
| 6 |
| Ẹnikan o si wi fun u pe, Ọgbẹ́ kini wọnyi li ọwọ rẹ? On o si dahùn pe, Wọnyi ni a ti ṣá mi ni ile awọn ọrẹ́ mi. |
| 7 |
| Dide, iwọ idà, si olùṣọ-agùtan mi, ati si ẹniti iṣe ẹnikeji mi, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi; kọlù olùṣọ-agùtan, awọn àgutan a si tuká: emi o si yi ọwọ mi si awọn kékèké. |
| 8 |
| Yio si ṣe, ni gbogbo ilẹ, li Oluwa wi, a o ké apá meji ninu rẹ̀ kuro yio si kú; ṣugbọn apá kẹta yio kù ninu rẹ̀. |
| 9 |
| Emi o si mu apá kẹta na là ãrin iná, emi o si yọ́ wọn bi a ti yọ́ fàdakà, emi o si dán wọn wò, bi a ti idán wura wò: nwọn o si pè orukọ mi, emi o si gbọ́ wọn: emi o wipe, Awọn enia mi ni: awọn o si wipe, Oluwa li Ọlọrun mi. |
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/zechariah/013.mp3
14
13