Awọn enia na si bá Ọlọrun, ati Mose sọ̀ pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi mú wa gòke lati Egipti jade wá lati kú li aginjù? nitoripe àkara kò sí, bẹ̃ni kò sí omi; onjẹ futẹfutẹ yi si sú ọkàn wa.
Nitorina li awọn enia na ṣe tọ̀ Mose wá, nwọn si wipe, Awa ti ṣẹ̀, nitoriti awa ti bá OLUWA ati iwọ sọ̀; gbadura si OLUWA ki o mú ejò wọnyi kuro lọdọ wa. Mose si gbadura fun awọn enia na.
Lati ibẹ̀ lọ nwọn ṣí, nwọn si dó si ìha keji Arnoni, ti mbẹ li aginjù, ti o ti àgbegbe awọn ọmọ Amori wá: nitoripe Arnoni ni ipinlẹ Moabu, lãrin Moabu ati awọn Amori.
Jẹ ki emi là ilẹ rẹ kọja lọ: awa ki yio yà sinu oko, tabi ọgba-àjara; awa ki yio mu ninu omi kanga: ọ̀na opópo ọba li a o gbà, titi awa o fi kọja ipinlẹ rẹ.
Sihoni kò si jẹ ki Israeli ki o là àgbegbe rẹ̀ kọja: ṣugbọn Sihoni kó gbogbo awọn enia rẹ̀ jọ, nwọn si jade tọ̀ Israeli lọ li aginjù, o si wá si Jahasi, o bá Israeli jà.
Egbé ni fun iwọ, Moabu! Ẹ gbé, ẹnyin enia Kemoṣi: on ti fi awọn ọmọ rẹ̀ ọkunrin bi isansa, ati awọn ọmọ rẹ̀ obinrin bi igbekun, fun Sihoni ọba awọn ọmọ Amori.
OLUWA si wi fun Mose pe, Máṣe bẹ̀ru rẹ̀: nitoripe mo ti fi on lé ọ lọwọ, ati gbogbo awọn enia rẹ̀, ati ilẹ rẹ̀; ki iwọ ki o si ṣe si i bi iwọ ti ṣe si Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, ti ngbé Heṣboni.