|
| 1 |
|
| OLÚWA sọ fún Mósè pé, |
|
| 2 |
|
| “Pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí o sì sọ fún wọn pé: ‘Tí ẹ bá wọ Kénánì, ilẹ̀ tí a ó fi fún yín, gẹ́gẹ́ bí ogún yín yóò ní ààlà wọn yí: |
|
| 3 |
|
| “ ‘Ìhà gúṣù yín yóò bọ́ sí ara ihà Ṣínì lẹ́bá Édómù, àti ìlà-oòrùn, ààlà ìhà-gúsù yóò bẹ̀rẹ̀ láti òpin Òkun Iyọ̀, |
|
| 4 |
|
| Kọjá lọ sí Síkọ́píọ́nì, tẹ̀ṣíwájú lọ si Sínì: kó bọ́ si gúsù Kadesi-Báníyà, kí o sì dé Hasari-Ádárò, kí o sì kọjá sí Ásímónì. |
|
| 5 |
|
| Níbẹ̀ ni yóò ti padà, papọ̀ mọ́ odò Éjíbítì, tí yóò sì parí ní òpin Òkun. |
|
| 6 |
|
| “ ‘Ìhà ìwọ̀ oòrùn yín yóò jẹ́ òpin lórí Òkun ńlá. Èyí yóò jẹ́ ààlà yín lórí ìhà-ìwọ̀ oòrùn: |
|
| 7 |
|
| “ ‘Fún ààlà ìhà-àríwá, fa ìlà láti òkun ńlá lọ sí orí òkè Hórì |
|
| 8 |
|
| Àti láti orí-òkè Hórì sí Lébò Hámátì. Nígbà náà ààlà náà yóò lọ sí Sédádì, |
|
| 9 |
|
| Tẹ̀ṣíwájú lọ sí Sífírónì, kí o sì fò pín si ní Hasari-Énánì, Èyí yóò jẹ́ ààlà tìrẹ ní ìhà àríwá. |
|
| 10 |
|
| “ ‘Kí ẹ sì sàmì sí ilẹ̀ ti yín ní ìhà ìlà oòrùn láti Hasari-Énánì lọ dé Ṣéfámù. |
|
| 11 |
|
| Ààlà náà yóò ti Séfámù sọ̀kalẹ̀ wá lọ sí Ríbílà ní ìhà-ìlà oòrùn Háínì, kí o sì sọ̀kalẹ̀ lọ dé ìhà Òkun Kínérétì ní ìhà ìlà oòrùn. |
|
| 12 |
|
| Nígbà náà, ààlà náà yóò sọ̀kalẹ̀ lọ sí apá Jọ́dánì, yóò sì dópin nínú Òkun. “ ‘Èyí yóò jẹ́ ilẹ̀ yín, pẹ̀lú ààlà tirẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà.’ ” |
|
| 13 |
|
| Mósè pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Yan ilẹ̀ yìí pẹ̀lú kèké gẹ́gẹ́ bí ìní ogún: OLÚWA ti paláṣẹ láti fi fún ẹ̀yà mẹ́san, àti ààbọ̀. |
|
| 14 |
|
| Nítorí ará ilẹ ẹ̀yà ti Rúbẹ́nì, ẹ̀yà ti Gádì àti ẹ̀yà ààbọ̀ ti Mánásè ti gba ogún ti wọn. |
|
| 15 |
|
| Ẹ̀yà méjèèjì àti ààbọ̀ yìí ti gba ogún ti wọn ní ìhà Jódánì létí i Jéríkò, Gábásì, ní ìhà ìlà oòrùn.” |
|
| 16 |
|
| OLÚWA sọ fún Mósè pé, |
|
| 17 |
|
| “Èyí ni orúkọ àwọn ọkùnrin náà tí yóò pín ilẹ̀, náà fún yín gẹ́gẹ́ bí ogún: Élíásárì àlùfáà àti Jóṣúà ọmọ Núnì. |
|
| 18 |
|
| Kí o sì yan olórí kan nínú ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan láti pín ilẹ̀ náà. |
|
| 19 |
|
| Èyí ni orúkọ wọn: Kálẹ́bù ọmọ Jéfúnè, láti ẹ̀yà Júdà; |
|
| 20 |
|
| Ṣémúélì ọmọ Ámíhúdì, láti ẹ̀yà Ṣíméónì; |
|
| 21 |
|
| Élídádì ọmọ Kísílónì, láti ẹ̀yà Bẹ́ńjámínì; |
|
| 22 |
|
| Búkì ọmọ Jógílì, láti ẹ̀yà olórí àwọn ọmọ Dánì; |
|
| 23 |
|
| Háníélì ọmọ Éfódù, láti ẹ̀yà Mánásè, olórí àwọn ọmọ Jóṣẹ́fù, |
|
| 24 |
|
| Kémúélì ọmọ Ṣífílánì, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ, Éfúráímù, ọmọ Jóṣẹ́fù; |
|
| 25 |
|
| Élísáfánì ọmọ Pánákì, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Ṣébúlunì; |
|
| 26 |
|
| Pátíélì ọmọ Ásánì, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísákárì; |
|
| 27 |
|
| Áhíhúdù ọmọ Ṣélómì, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Áṣérì; |
|
| 28 |
|
| Pédàhẹ́lì ọmọ Ámíhúdì, olórí ẹ̀yà àwọn ọmọ Náfitalì.” |
|
| 29 |
|
| Èyí ni àwọn ẹni tí OLÚWA yàn láti pín ogún náà fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ Kénánì. |
|
|
|
|