Nígbà tí wọn kò sì le dé ọ̀dọ̀ Jésù, nítorí ọ̀pọ̀ ènìyàn, wọ́n dá òrùlé ilé lu ní ọ̀gangan ibi tí Jésù wà. Wọ́n sì sọ ọkùnrin arọ náà kalẹ̀ ti òun ti ẹní rẹ̀ níwájú Jésù.
Lojú kan náà bí Jésù tí wòye nínú ọkàn rẹ̀ pé wọn ń gbèrò bẹ́ẹ̀ ní àárín ara wọn, ó wí fún wọn pé, “È é ṣe tí ẹ̀yìn fí ń ro nǹkan wọ̀nyí nínú ọkàn yín?
Lójúkan-náà, ọkùnrin náà fò sókè fún ayọ̀. Ó gbé ẹní rẹ̀. Ó sì jáde lọ lojú gbogbo wọn. Èyí sì ya gbogbo wọn lẹ́nu tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n sì yin Ọlọ́run lógo wí pé, “Àwa kò rí irú èyí rí!”
Bí ó ti ń rin etí òkun lọ sókè, ó rí Léfì ọmọ Álíféù tí ó jókòó nínú àgọ́ níbi tí ó ti ń gba owó orí, Jésù sì wí fún un pé, “Tẹ̀ lé mi,” Léfì dìde, ó sì ń tẹ̀lé e.
Ó si ṣe, bí ó sì ti jókòó tí oúnjẹ ni ilé Léfì, ọ̀pọ̀ àwọn agbowó òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ wá bá Jésù jókòó pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, nítorí ti wọn pọ̀ ti wọn tẹ̀lé e.
Nígbà tí àwọn olùkọ òfin àti àwọn Farisí rí ì tí ó ń bá àwọn agbowó-òde àti àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun, wọn wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “È é ti rí tí ó fi ń bá àwọn agbowó-òde àti ẹlẹ́ṣẹ̀ jẹun?”
Nígbà tí Jésù gbọ́, ó sọ fún wọn wí pé, “Àwọn tí ara wọ́n dá kò wa oníṣègùn, bí ko ṣe àwọn tí ara wọn kò dá. Èmi kò wá lati sọ fún àwọn ènìyàn rere láti ronúpìwàdà, bí kò ṣe àwọn ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀.”
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù àti àwọn Farisí a máa gbààwẹ̀: Àwọn ènìyàn kan sì wá, wọ́n sì bi í pé, “È é ṣe tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jòhánù àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Farisí fi ń gbààwẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn ọmọ ẹ̀yin rẹ kò gbààwẹ̀?”
“Kò si ẹni tí ń fi ìrépé aṣọ túntún lẹ ògbólógbo ẹ̀wù, bí ó ba se bẹ́ẹ̀, èyí túntún ti a fi lẹ̀ ẹ́ yóò fà ya kúrò lára ògbólógbòó, yíyọ́ rẹ̀ yóò sí burú púpọ̀ jù.
Kò sì sí ẹni tí ń fi ọtí wáìnì túntún sínú ìgò wáìni ògbólógbó. Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, ọtí wáìnì náà yóò fa ìgò náà ya, ọtí wáìnì a si dàànu, bákan náà ni ìgò náà, ṣùgbọ́n ọtí wáìnì tuntun ni a n fi sínú ìgò wáìnì tuntun.”
Bí ó tí wọ ilé Ọlọ́run lọ ni ọjọ́ Ábíátarì olórí àlùfáà, tí ó sì jẹ búrẹ́dì ìfihàn ti kò tọ́ fún un láti jẹ bí kò ṣe fún àwọn àlùfáà, ó sì tún fi fún àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀.”