Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| O si ṣe, nigbati ainiye ijọ enia pejọ pọ̀, tobẹ̃ ti nwọn ntẹ̀ ara wọn mọlẹ, o tètekọ́ wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ mã ṣọra nyin nitori iwukara awọn Farisi, ti iṣe agabagebe. |
| 2 |
| Kò si ohun ti a bò, ti a kì yio si fihàn; tabi ti o pamọ, ti a ki yio mọ̀. |
| 3 |
| Nitorina ohunkohun ti ẹnyin sọ li òkunkun, ni gbangba li a o gbé gbọ́; ati ohun ti ẹnyin ba sọ si etí ni ìkọkọ, lori orule li a o gbé kede rẹ̀. |
| 4 |
| Emi si wi fun nyin ẹnyin ọrẹ́ mi, Ẹ máṣe bẹ̀ru awọn ti ipa ara enia kú, lẹhin eyini ti nwọn kò si li eyiti nwọn le ṣe mọ́. |
| 5 |
| Ṣugbọn emi o si sọ ẹniti ẹnyin o bẹ̀ru fun nyin: Ẹ bẹru ẹniti o lagbara lẹhin ti o ba pani tan, lati wọ́ni lọ si ọrun apadi; lõtọ ni mo wi fun nyin, On ni ki ẹ bẹru. |
| 6 |
| Ologoṣẹ marun ki a ntà li owo idẹ wẹ́wẹ meji? a kò si gbagbé ọkan ninu wọn niwaju Ọlọrun? |
| 7 |
| Ṣugbọn gbogbo irun ori nyin li a kà pé ṣanṣan. Nitorina ki ẹ máṣe bẹ̀ru: ẹnyin ni iye lori jù ologoṣẹ pipọ lọ. |
| 8 |
| Mo si wi fun nyin pẹlu, Ẹnikẹni ti o ba jẹwọ mi niwaju enia, Ọmọ-ẹnia yio si jẹwọ rẹ̀ niwaju awọn angẹli Ọlọrun: |
| 9 |
| Ṣugbọn ẹniti o ba sẹ́ mi niwaju enia, a o sẹ́ ẹ niwaju awọn angẹli Ọlọrun. |
| 10 |
| Ati ẹnikẹni ti o ba sọ̀rọ-òdi si Ọmọ-enia, a o dari rẹ̀ jì i: ṣugbọn ẹnikẹni ti o ba sọrọ-odi si Ẹmí Mimọ́, a kì yio dari rẹ̀ jì i. |
| 11 |
| Nigbati nwọn ba si mu nyin wá si sinagogu, ati siwaju awọn olori, ati awọn alaṣẹ, ẹ máṣe ṣàniyàn pe, bawo tabi ohùn kili ẹnyin ó da, tabi kili ẹnyin o wi: |
| 12 |
| Nitori Ẹmí Mimọ́ yio kọ́ nyin ni wakati kanna li ohun ti o yẹ ki ẹ wi. |
| 13 |
| Ọkan ninu awujọ si wi fun u pe, Olukọni, sọ fun arakunrin mi ki o pín mi li ogún. |
| 14 |
| O si wi fun u pe, ọkunrin yi, tali o fi mi jẹ onidajọ tabi olùpín-ogún wá fun nyin? |
| 15 |
| O si wi fun wọn pe, Kiyesara ki ẹ si mã ṣọra nitori ojukòkoro: nitori igbesi aiye enia ki iduro nipa ọ̀pọ ohun ti o ni. |
| 16 |
| O si pa owe kan fun wọn, wipe, Ilẹ ọkunrin kan ọlọrọ̀ so eso ọ̀pọlọpọ: |
| 17 |
| O si rò ninu ara rẹ̀, wipe, Emi o ti ṣe, nitoriti emi kò ni ibiti emi o gbé kó eso mi jọ si? |
| 18 |
| O si wipe, Eyi li emi o ṣe: emi o wó aká mi palẹ, emi o si kọ́ eyi ti o tobi; nibẹ̀ li emi o gbé tò gbogbo eso ati ọrọ̀ mi jọ si. |
| 19 |
| Emi o si wi fun ọkàn mi pe, Ọkàn, iwọ li ọrọ̀ pipọ ti a tò jọ fun ọ̀pọ ọdún; simi mã jẹ, mã mu, mã yọ̀. |
| 20 |
| Ṣugbọn Ọlọrun wi fun u pe, Iwọ aṣiwere, li oru yi li a o bère ẹmi rẹ lọwọ rẹ: njẹ titani nkan wọnni yio ha ṣe, ti iwọ ti pèse silẹ? |
| 21 |
| Bẹ̃ li ẹniti o tò iṣura jọ fun ara rẹ̀, ti ko si li ọrọ̀ lọdọ Ọlọrun. |
| 22 |
| O si wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Nitorina mo wi fun nyin pe, ẹ máṣe ṣaniyàn nitori ẹmí nyin pe, kili ẹnyin ó jẹ; tabi nitori ara nyin pe, kili ẹnyin ó fi bora. |
| 23 |
| Ẹmí sa jù onjẹ lọ, ara si jù aṣọ lọ. |
| 24 |
| Ẹ kiyesi awọn ìwo: nwọn kì ifọnrugbin, bẹ̃ni nwọn ki kore; nwọn kò li aká, bẹ̃ni nwọn kò li abà; Ọlọrun sá mbọ́ wọn: melomelo li ẹnyin sàn jù ẹiyẹ lọ? |
| 25 |
| Tani ninu nyin nipa aniyan ṣiṣe ti o le fi igbọnwọ kan kún ọjọ aiyé rẹ̀? |
| 26 |
| Njẹ bi ẹnyin kò le ṣe eyi ti o kere julọ, ẽṣe ti ẹnyin fi nṣaniyan nitori iyokù? |
| 27 |
| Ẹ kiyesi awọn lili bi nwọn ti ndàgba: nwọn ki iṣiṣẹ nwọn ki iranwu; ṣugbọn ki emi wi fun nyin, a kò ṣe Solomoni pãpã li ọṣọ́ ni gbogbo ogo rẹ̀ to ọkan ninu wọnyi. |
| 28 |
| Njẹ bi Ọlọrun ba wọ̀ koriko igbẹ́ li aṣọ tobẹ̃ eyiti o wà loni, ti a si gbá a sinu ina lọla; melomelo ni yio wọ̀ nyin li aṣọ, ẹnyin onigbagbọ́ kekere? |
| 29 |
| Ẹ má si ṣe bere ohun ti ẹnyin ó jẹ, tabi ohun ti ẹnyin o mu, ki ẹnyin ki o má si ṣiyemeji. |
| 30 |
| Nitori gbogbo nkan wọnyi ni awọn orilẹ-ède aiye nwá kiri: Baba nyin si mọ̀ pe, ẹnyin nfẹ nkan wọnyi. |
| 31 |
| Ṣugbọn ẹ mã wá ijọba Ọlọrun; gbogbo nkan wọnyi li a o si fi kún nyin. |
| 32 |
| Má bẹ̀ru, agbo kekere; nitori didùn inu Baba nyin ni lati fi ijọba fun nyin. |
| 33 |
| Ẹ tà ohun ti ẹnyin ni, ki ẹnyin ki o si tọrẹ ãnu; ki ẹnyin ki o si pèse àpo fun ara nyin, ti kì igbó, iṣura li ọrun ti kì itán, nibiti olè kò le sunmọ, ati ibiti kòkoro kì iba a jẹ. |
| 34 |
| Nitori nibiti iṣura nyin gbé wà, nibẹ̀ li ọkàn nyin yio gbé wà pẹlu. |
| 35 |
| Ẹ di amure nyin, ki fitila nyin ki o si mã jo: |
| 36 |
| Ki ẹnyin tikara nyin ki o dabi ẹniti nreti oluwa wọn, nigbati on o pada ti ibi iyawo de; pe, nigbati o ba de, ti o si kànkun, ki nwọn ki o le ṣí i silẹ fun u lọgan. |
| 37 |
| Ibukun ni fun awọn ọmọ-ọdọ wọnni nigbati oluwa na ba de ti yio ba ki nwọn ki o ma ṣọna: lõtọ ni mo wi fun nyin, yio di ara rẹ̀ li amure, yio si mu wọn joko lati jẹun, yio si jade wá lati ṣe iranṣẹ fun wọn. |
| 38 |
| Bi o ba si de nigba iṣọ keji, tabi ti o si de nigba iṣọ kẹta, ti o si ba wọn bẹ̃, ibukun ni fun awọn ọmọ-ọdọ wọnni. |
| 39 |
| Ṣugbọn ẹ mọ̀ eyi pe, bãle ile iba mọ̀ wakati ti olè yio wá, on iba ma ṣọna, kì ba ti jẹ ki a lu ile on já. |
| 40 |
| Nitorina ki ẹnyin ki o mura pẹlu: Nitori Ọmọ-enia mbọ̀ ni wakati ti ẹnyin kò daba. |
| 41 |
| Peteru si wipe, Oluwa, iwọ pa owe yi fun wa, tabi fun gbogbo enia? |
| 42 |
| Oluwa si dahùn wipe, Tani olõtọ ati ọlọ́gbọn iriju na, ti oluwa rẹ̀ fi jẹ olori agbo ile rẹ̀, lati ma fi ìwọn onjẹ wọn fun wọn li akokò? |
| 43 |
| Ibukun ni fun ọmọ-ọdọ na, nigbati oluwa rẹ̀ ba de, ti yio ba a ki o ma ṣe bẹ̃. |
| 44 |
| Lõtọ ni mo wi fun nyin, yio si fi i jẹ olori ohun gbogbo ti o ni. |
| 45 |
| Ṣugbọn bi ọmọ-ọdọ na ba wi li ọkàn rẹ̀ pe, Oluwa mi yẹ̀ igba atibọ̀ rẹ̀; ti o si bẹ̀rẹ si ilù awọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, ti o si bẹ̀rẹ si ijẹ ati si imu amupara; |
| 46 |
| Oluwa ọmọ-ọdọ na yio de li ọjọ ti kò reti rẹ̀, ati ni wakati ti kò daba, yio si jẹ ẹ niya gidigidi, yio si yàn ipò rẹ̀ pẹlu awọn alaigbagbọ́. |
| 47 |
| Ati ọmọ-ọdọ na, ti o mọ̀ ifẹ oluwa rẹ̀, ti kò si mura silẹ ti kò si ṣe gẹgẹ bi ifẹ rẹ̀, on li a o nà pipọ. |
| 48 |
| Ṣugbọn eyi ti kò mọ̀, ti o ṣe ohun ti o yẹ si lilu, on li a o lù niwọn. Nitori ẹnikẹni ti a fun ni pipọ, lọdọ rẹ̀ li a o gbé bère pipọ: lọdọ ẹniti a ba gbé fi pipọ si, lọdọ rẹ̀ li a o gbé bère si i. |
| 49 |
| Iná li emi wá lati fọ̀n si aiye; kili emi si nfẹ bi a ba ti da a ná? |
| 50 |
| Ṣugbọn emi ni baptismu kan ti a o fi baptisi mi; ara ti nni mi to titi yio fi pari! |
| 51 |
| Ẹnyin ṣebi alafia li emi wá fi si aiye? mo wi fun nyin, Bẹ̃kọ; ki a sá kuku pe iyapa: |
| 52 |
| Nitori lati isisiyi lọ, enia marun yio wà ni ile kanna ti a o yà ni ipa, mẹta si meji, ati meji si mẹta. |
| 53 |
| A o yà baba ni ipa si ọmọ rẹ̀ ọkunrin, ati ọmọkunrin si baba; iya si ọmọbinrin rẹ̀, ati ọmọbinrin si iya rẹ̀; iyakọ si iyawo rẹ̀, ati iyawo si iyako rẹ̀. |
| 54 |
| O si wi fun ijọ enia pẹlu pe, Nigbati ẹnyin ba ri awọsanma ti o ṣú ni ìha ìwọ-õrùn, ọgan ẹnyin a ni, Ọwara òjo mbọ̀; a si ri bẹ̃. |
| 55 |
| Nigbati afẹfẹ gusù ba nfẹ, ẹnyin a ni, Õru yio mu; a si ṣẹ. |
| 56 |
| Ẹnyin agabagebe, ẹnyin le moye oju ọrun ati ti aiye; ẽhatiṣe ti ẹnyin kò le mọ̀ akokò yi? |
| 57 |
| Ẽha si ti ṣe ti ẹnyin tikara nyin ko fi rò ohun ti o tọ́? |
| 58 |
| Nigbati iwọ ba mbá ọtá rẹ lọ sọdọ olóri, mura li ọ̀na ki a le gbà ọ lọwọ rẹ̀; ki o máṣe fi ọ le onidajọ lọwọ, ki onidajọ máṣe fi ọ le ẹṣọ lọwọ, on a si tì ọ sinu tubu. |
| 59 |
| Ki emi ki o wi fun ọ, iwọ ki yio jade kuro nibẹ̀, titi iwọ o fi san õkan ti o ba kù. |
|
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/luke/012.mp3
24
12