Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| ARA ọkunrin kan si ṣe alaidá, Lasaru, ara Betani, ti iṣe ilu Maria ati Marta arabinrin rẹ̀. |
| 2 |
| (Maria na li ẹniti o fi ororo ikunra kùn Oluwa, ti o si fi irun ori rẹ̀ nù ẹsẹ rẹ̀ nù, arakunrin rẹ̀ ni Lasaru iṣe, ara ẹniti kò dá.) |
| 3 |
| Nitorina awọn arabinrin rẹ̀ ranṣẹ si i, wipe, Oluwa, wo o, ara ẹniti iwọ fẹran kò da. |
| 4 |
| Nigbati Jesu si gbọ́, o wipe, Aisan yi kì iṣe si ikú, ṣugbọn fun ogo Ọlọrun, ki a le yìn Ọmọ Ọlọrun logo nipasẹ rẹ̀. |
| 5 |
| Jesu si fẹran Marta, ati arabinrin rẹ̀, ati Lasaru. |
| 6 |
| Nitorina nigbati o ti gbọ́ pe, ara rẹ̀ kò da, o gbé ijọ meji si i nibikanna ti o gbé wà. |
| 7 |
| Njẹ lẹhin eyi li o wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ jẹ ki a tún pada lọ si Judea. |
| 8 |
| Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si wi fun u pe, Rabbi, ni lọ̃lọ̃ yi li awọn Ju nwá ọ̀na ati sọ ọ li okuta; iwọ si ntún pada lọ sibẹ̀? |
| 9 |
| Jesu dahún pe, Wakati mejila ki mbẹ ninu ọsán kan? Bi ẹnikan ba rìn li ọsán, kì yio kọsẹ̀, nitoriti o ri imọlẹ aiye yi. |
| 10 |
| Ṣugbọn bi ẹnikan ba rìn li oru, yio kọsẹ̀, nitoriti kò si imọlẹ ninu rẹ̀. |
| 11 |
| Nkan wọnyi li o sọ: lẹhin eyini o si wi fun wọn pe, Lasaru ọrẹ́ wa sùn; ṣugbọn emi nlọ ki emi ki o le jí i dide ninu orun rẹ̀. |
| 12 |
| Nitorina awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Oluwa, bi o ba ṣe pe o sùn, yio sàn. |
| 13 |
| Ṣugbọn Jesu nsọ ti ikú rẹ̀: ṣugbọn nwọn rò pe, o nsọ ti orun sisun. |
| 14 |
| Nigbana ni Jesu wi fun wọn gbangba pe, Lasaru kú. |
| 15 |
| Emi si yọ̀ nitori nyin, ti emi kò si nibẹ̀, Ki ẹ le gbagbọ́; ṣugbọn ẹ jẹ ki a lọ sọdọ rẹ̀. |
| 16 |
| Nitorina Tomasi, ẹniti a npè ni Didimu, wi fun awọn ọmọ-ẹhin ẹgbẹ rẹ̀ pe, Ẹ jẹ ki awa na lọ, ki a le ba a kú pẹlu. |
| 17 |
| Nitorina nigbati Jesu de, o ri pe a ti tẹ́ ẹ sinu ibojì ni ijọ mẹrin na. |
| 18 |
| Njẹ Betani sunmọ Jerusalemu to furlongi mẹdogun: |
| 19 |
| Ọ̀pọ ninu awọn Ju si wá sọdọ Marta ati Maria, lati tù wọn ninu nitori ti arakunrin wọn. |
| 20 |
| Nitorina nigbati Marta gbọ́ pe Jesu mbọ̀ wá, o jade lọ ipade rẹ̀: ṣugbọn Maria joko ninu ile. |
| 21 |
| Nigbana ni Marta wi fun Jesu pe, Oluwa, ibaṣepe iwọ ti wà nihin, arakunrin mi kì ba tí kú. |
| 22 |
| Ṣugbọn nisisiyi na, mo mọ̀ pe, ohunkohun ti iwọ ba bère lọwọ Ọlọrun, Ọlọrun yio fifun ọ. |
| 23 |
| Jesu wi fun u pe, Arakunrin rẹ yio jinde. |
| 24 |
| Marta wi fun u pe, mo mọ̀ pe yio jinde li ajinde nigbẹhin ọjọ. |
| 25 |
| Jesu wi fun u pe, Emi ni ajinde, ati ìye: ẹniti o ba gbà mi gbọ́, bi o tilẹ kú, yio yè: |
| 26 |
| Ẹnikẹni ti o mbẹ lãye, ti o si gbà mi gbọ́, kì yio kú lailai. Iwọ gbà eyi gbọ́? |
| 27 |
| O wi fun u pe, Bẹ̃ni, Oluwa: emi gbagbọ́ pe, iwọ ni Kristi na Ọmọ Ọlọrun, ẹniti mbọ̀ wá aiye. |
| 28 |
| Nigbati o si ti wi eyi tan, o lọ, o si pè Maria arabinrin rẹ̀ sẹhin wipe, Olukọni de, o si npè ọ. |
| 29 |
| Nigbati o gbọ́, o dide lọgan, o si wá sọdọ rẹ̀. |
| 30 |
| Jesu kò sá ti iwọ̀ ilu, ṣugbọn o wà nibikanna ti Marta pade rẹ̀. |
| 31 |
| Nitorina awọn Ju ti o wà lọdọ rẹ̀ ninu ile, ti nwọn ntù u ninu, nigbati nwọn ri ti Maria dide kánkan, ti o si jade, nwọn tẹ̀le e, nwọn ṣebi o nlọ si ibojì lọ isọkun nibẹ̀. |
| 32 |
| Nigbati Maria si de ibiti Jesu gbé wà, ti o si ri i, o wolẹ lẹba ẹsẹ rẹ̀, o wi fun u pe, Oluwa, ibaṣepe iwọ ti wà nihin, arakunrin mi kò ba má kú. |
| 33 |
| Njẹ nigbati Jesu ri i, ti o nsọkun, ati awọn Ju ti o ba a wá nsọkun pẹlu rẹ̀, o kerora li ọkàn rẹ̀, inu rẹ̀ si bajẹ, |
| 34 |
| O si wipe, Nibo li ẹnyin gbé tẹ́ ẹ si? Nwọn si wi fun u pe, Oluwa, wá wò o. |
| 35 |
| Jesu sọkun. |
| 36 |
| Nitorina awọn Ju wipe, sa wo o bi o ti fẹràn rẹ̀ to! |
| 37 |
| Awọn kan ninu wọn si wipe, Ọkunrin yi, ẹniti o là oju afọju, kò le ṣe ki ọkunrin yi má ku bi? |
| 38 |
| Nigbana ni Jesu tún kerora ninu ara rẹ̀, o wá si ibojì. O si jẹ ihò, a si gbé okuta le ẹnu rẹ̀. |
| 39 |
| Jesu wipe, Ẹ gbé okuta na kuro. Marta, arabinrin ẹniti o kú na wi fun u pe, Oluwa, o ti nrùn nisisiyi: nitoripe o di ijọ mẹrin ti o ti kú. |
| 40 |
| Jesu wi fun u pe, Emi kò ti wi fun ọ pe, bi iwọ ba gbagbọ́, iwọ o ri ogo Ọlọrun? |
| 41 |
| Nigbana ni nwọn gbé okuta na kuro nibiti a gbe tẹ́ okú na si. Jesu si gbé oju rẹ̀ soke, o si wipe, Baba, mo dupẹ lọwọ rẹ, nitoriti iwọ gbọ́ ti emi. |
| 42 |
| Emi si ti mọ̀ pe, iwọ a ma gbọ́ ti emi nigbagbogbo: ṣugbọn nitori ijọ enia ti o duro yi ni mo ṣe wi i, ki nwọn ki o le gbagbọ́ pe iwọ li o rán mi. |
| 43 |
| Nigbati o si ti wi bẹ̃ tan, o kigbe li ohùn rara pe, Lasaru, jade wá. |
| 44 |
| Ẹniti o kú na si jade wá, ti a fi aṣọ okú dì tọwọ tẹsẹ a si fi gèle dì i loju. Jesu wi fun wọn pe, Ẹ tú u, ẹ si jẹ ki o mã lọ. |
| 45 |
| Nitorina li ọ̀pọ awọn Ju ti o wá sọdọ Maria, ti nwọn ri ohun ti Jesu ṣe, nwọn gbà a gbọ. |
| 46 |
| Ṣugbọn awọn ẹlomiran ninu wọn tọ̀ awọn Farisi lọ, nwọn si sọ fun wọn ohun ti Jesu ṣe. |
| 47 |
| Nigbana li awọn olori alufa ati awọn Farisi pè igbimọ jọ, nwọn si wipe, Kili awa nṣe? nitori ọkunrin yi nṣe ọ̀pọlọpọ iṣẹ àmi. |
| 48 |
| Bi awa ba jọwọ rẹ̀ bẹ̃, gbogbo enia ni yio gbà a gbọ́: awọn ará Romu yio si wá gbà ilẹ ati orilẹ-ède wa pẹlu. |
| 49 |
| Ṣugbọn Kaiafa, ọkan ninu wọn, ẹniti iṣe olori alufa li ọdún na, o wi fun wọn pe, Ẹnyin kò mọ̀ ohunkohun rara. |
| 50 |
| Bẹ̃ni ẹ kò si ronu pe, o ṣànfani fun wa, ki enia kan kú fun awọn enia, ki gbogbo orilẹ-ède ki o má bà ṣegbé. |
| 51 |
| Ki iṣe fun ara rẹ̀ li o sọ eyi: ṣugbọn bi o ti jẹ olori alufa li ọdún na, o sọtẹlẹ pe, Jesu yio kú fun orilẹ-ède na: |
| 52 |
| Ki si iṣe kìki fun orilẹ-ède na nikan, ṣugbọn pẹlu ki o le kó awọn ọmọ Ọlọrun ti a ti funka kiri jọ li ọkanṣoṣo. |
| 53 |
| Nitorina lati ọjọ na lọ ni nwọn ti jọ gbìmọ pọ̀ lati pa a. |
| 54 |
| Nitorina Jesu kò rìn ni gbangba larin awọn Ju mọ́; ṣugbọn o ti ibẹ̀ lọ si igberiko kan ti o sunmọ aginjù, si ilu nla ti à npè ni Efraimu, nibẹ̀ li o si wà pẹlu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀. |
| 55 |
| Ajọ irekọja awọn Ju si sunmọ etile: ọ̀pọlọpọ lati igberiko wá si gòke lọ si Jerusalemu ṣiwaju irekọja, lati yà ara wọn si mimọ́. |
| 56 |
| Nigbana ni nwọn nwá Jesu, nwọn si mba ara wọ́n sọ, bi nwọn ti duro ni tẹmpili, wipe, Ẹnyin ti rò o si? pe kì yio wá si ajọ? |
| 57 |
| Njẹ awọn olori alufa ati awọn Farisi ti paṣẹ pe bi ẹnikan ba mọ̀ ibi ti o gbé wà, ki o fi i hàn, ki nwọn ki o le mu u. |
|
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/john/011.mp3
21
11