Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| NIGBATI ariwo na si rọlẹ, Paulu ranṣẹ pè awọn ọmọ-ẹhin, o si gbà wọn ni iyanju, o dagbere fun wọn, o dide lati lọ si Makedonia. |
| 2 |
| Nigbati o si ti là apa ìha wọnni kọja, ti o si ti fi ọ̀rọ pipọ gbà wọn ni iyanju, o wá si ilẹ Hellene. |
| 3 |
| Nigbati o si duro nibẹ̀ li oṣù mẹta, ti awọn Ju si dèna dè e, bi o ti npete ati ba ti ọkọ̀ lọ si Siria, o pinnu rẹ̀ lati ba ti Makedonia pada lọ. |
| 4 |
| Sopateru ara Berea ọmọ Parru si ba a lọ de Asia; ati ninu awọn ara Tessalonika, Aristarku on Sekundu; ati Gaiu ara Derbe, ati Timotiu; ati ara Asia, Tikiku on Trofimu. |
| 5 |
| Ṣugbọn awọn wọnyi ti lọ ṣiwaju, nwọn nduro dè wa ni Troa. |
| 6 |
| Awa si ṣikọ̀ lati Filippi wá lẹhin ọjọ aiwukara, a si de ọdọ wọn ni Troasi ni ijọ karun; nibiti awa gbé duro ni ijọ meje. |
| 7 |
| Ati ni ọjọ ikini ọ̀sẹ nigbati awọn ọmọ-ẹhin pejọ lati bù akara, Paulu si wasu fun wọn, o mura ati lọ ni ijọ keji: o si fà ọ̀rọ rẹ̀ gùn titi di arin ọganjọ. |
| 8 |
| Fitilà pipọ si wà ni yàrá oke na, nibiti a gbé pejọ si. |
| 9 |
| Ọdọmọkunrin kan ti a npè ni Eutiku si joko li oju ferese, orun si wọ̀ ọ lara: bi Paulu si ti pẹ ni iwasu, o ta gbọ́ngbọ́n loju orun, o ṣubu lati oke kẹta wá silẹ, a si gbé e dide li okú. |
| 10 |
| Nigbati Paulu si sọkalẹ, o wolẹ bò o, o gbá a mọra, o ni, Ẹ má yọ ara nyin lẹnu; nitori ẹmí rẹ̀ mbẹ ninu rẹ̀. |
| 11 |
| Nigbati o si tún gòke lọ, ti o si bù akara, ti o si jẹ, ti o si sọ̀rọ pẹ titi o fi di afẹmọjumọ́, bẹ̃li o lọ. |
| 12 |
| Nwọn si mu ọmọkunrin na bọ̀ lãye, inu nwọn si dun gidigidi. |
| 13 |
| Nigbati awa si ṣaju, awa si ṣikọ̀ lọ si Asso, nibẹ̀ li a nfẹ gbà Paulu si ọkọ̀: nitori bẹ̃li o ti pinnu rẹ̀, on tikararẹ̀ nfẹ ba ti ẹsẹ lọ. |
| 14 |
| Nigbati o pade wa ni Asso, ti a si ti gbà a si ọkọ̀, a lọ si Mitilene. |
| 15 |
| Nigbati a si ṣikọ̀ nibẹ̀, ni ijọ keji a de ọkankan Kio; ni ijọ keji rẹ̀ a de Samo, a si duro ni Trogillioni; ni ijọ keji rẹ̀ a si de Miletu. |
| 16 |
| Paulu sá ti pinnu rẹ̀ lati mu ọkọ̀ lọ niha Efesu, nitori ki o ma ba fi igba na joko ni Asia: nitori o nyára bi yio ṣe iṣe fun u, lati wà ni Jerusalemu li ọjọ Pentikosti. |
| 17 |
| Ati lati Miletu o ranṣẹ si Efesu, lati pè awọn alàgba ijọ wá sọdọ rẹ̀. |
| 18 |
| Nigbati nwọn si de ọdọ rẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹnyin tikaranyin mọ̀, lati ọjọ ikini ti mo ti de Asia, bi emi ti ba nyin gbé, ni gbogbo akoko na, |
| 19 |
| Bi mo ti nfi ìrẹlẹ ọkàn gbogbo sìn Oluwa, ati omije pipọ, pẹlu idanwò, ti o bá mi, nipa ìdena awọn Ju: |
| 20 |
| Bi emi kò ti fà sẹhin lati sọ ohunkohun ti o ṣ'anfani fun nyin, ati lati mã kọ́ nyin ni gbangba ati lati ile de ile, |
| 21 |
| Ti mo nsọ fun awọn Ju, ati fun awọn Hellene pẹlu, ti ironupiwada sipa Ọlọrun, ati ti igbagbọ́ sipa Jesu Kristi Oluwa wa. |
| 22 |
| Njẹ nisisiyi, wo o, ọkàn mi nfà si ati lọ si Jerusalemu, laimọ̀ ohun ti yio bá mi nibẹ̀: |
| 23 |
| Bikoṣe bi Ẹmí Mimọ́ ti nsọ ni ilu gbogbo pe, ìde on ìya mbẹ fun mi. |
| 24 |
| Ṣugbọn emi kò kà ẹmi mi si nkan rara bi ohun ti o ṣọwọn fun mi, ki emi ki o ba le fi ayọ̀ pari ire-ije mi ati iṣẹ-iranṣẹ ti mo ti gbà lọdọ Jesu Oluwa, lati mã ròhin ihinrere ore-ọfẹ Ọlọrun. |
| 25 |
| Njẹ nisisiyi, wo o, emi mọ̀ pe gbogbo nyin, lãrin ẹniti emi ti nkiri wãsu ijọba Ọlọrun, kì yio ri oju mi mọ́. |
| 26 |
| Nitorina mo pè nyin ṣe ẹlẹri loni yi pe, ọrùn mi mọ́ kuro ninu ẹ̀jẹ enia gbogbo. |
| 27 |
| Nitoriti emi kò fà sẹhin lati sọ gbogbo ipinnu Ọlọrun fun nyin. |
| 28 |
| Ẹ kiyesara nyin, ati si gbogbo agbo ti Ẹmí Mimọ́ fi nyin ṣe alabojuto rẹ̀, lati mã tọju ijọ Ọlọrun, ti o ti fi ẹ̀jẹ ara rẹ̀ rà. |
| 29 |
| Nitoriti emi mọ̀ pe, lẹhin lilọ mi, ikõkò buburu yio wọ̀ ãrin nyin, li aidá agbo si. |
| 30 |
| Ati larin ẹnyin tikaranyin li awọn enia yio dide, ti nwọn o ma sọ̀rọ òdi, lati fà awọn ọmọ-ẹhin sẹhin wọn. |
| 31 |
| Nitorina ẹ mã ṣọra, ki ẹ si mã ranti pe, fun ọdún mẹta, emi kò dẹkun ati mã fi omije kìlọ fun olukuluku li ọsán ati li oru. |
| 32 |
| Njẹ nisisiyi, ará, mo fi nyin le Ọlọrun lọwọ ati ọ̀rọ ore-ọfẹ rẹ̀, ti o le gbe nyin duro, ti o si le fun nyin ni ini lãrin gbogbo awọn ti a sọ di mimọ́. |
| 33 |
| Emi kò ṣe ojukòkoro fadaka, tabi wura, tabi aṣọ ẹnikẹni. |
| 34 |
| Ẹnyin tikaranyin sá mọ̀ pe, ọwọ́ wọnyi li o ṣiṣẹ fun aini mi, ati ti awọn ti o wà pẹlu mi. |
| 35 |
| Ninu ohun gbogbo mo fi apẹrẹ fun nyin pe, nipa ṣiṣe iṣẹ bẹ̃, yẹ ki ẹ mã ràn awọn alailera lọwọ, ki ẹ si mã ranti ọ̀rọ Jesu Oluwa, bi on tikararẹ̀ ti wipe, Ati funni o ni ibukún jù ati gbà lọ. |
| 36 |
| Nigbati o si ti wi nkan wọnyi, o kunlẹ, o si ba gbogbo wọn gbadura. |
| 37 |
| Gbogbo wọn si sọkun gidigidi, nwọn si rọ̀ mọ́ Paulu li ọrùn, nwọn si fi ẹnu kò o li ẹnu, |
| 38 |
| Inu wọn si bajẹ julọ fun ọ̀rọ ti o sọ pe, nwọn kì yio ri oju on mọ́. Nwọn si sìn i lọ sinu ọkọ̀. |
|
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/acts/020.mp3
28
20