Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMY) 2014
|
| 1 |
| Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá ni èdè-àìyedè sí ẹnikejì rẹ̀, ó ha gbọdọ̀ lọ pè é lẹ́jọ́ níwájú àwọn aláìsòótọ́ bí, bí kò se níwájú àwọn ènìyàn mímọ́? |
| 2 |
| Ṣé ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn ẹni mímọ́ ni yóò ṣe ìdájọ́ ayé? Ǹjẹ́ bí ó ba ṣe ìpaṣẹ̀ yín ni a ti ṣe ìdájọ́ ayé, kí ni ìdí tí ẹ kò fi yanjú àwọn ọ̀rọ̀ kéékèèkéé wọ̀nyí láàrin ara yín. |
| 3 |
| Ẹ kò mọ̀ pé àwa ni a ó ṣe ìdájọ́ àwọn ańgẹ́lì ní? Mélòómélòó àwọn nǹkan tó wà nínú ayé yìí. |
| 4 |
| Nítorí náà, bí ẹ̀yin bá ni aáwọ̀ lórí ọ̀rọ̀ yìí, ẹ yan àwọn tí ó kéré jù nínú ìjọ láti dá irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀. |
| 5 |
| Mo sọ èyí kí ojú lè tì yín, Ṣe ó see se kí a máa rín ẹnìkan láàrin yín tí ó gbọ́n níwọ̀n láti ṣe idájọ́ èdè àìyedè láàrin àwọn onígbàgbọ́? |
| 6 |
| Ṣùgbọ́n dípò èyí, arákùnrin kan ń pe arákùnrin kejì lẹ́jọ́ sí ilé ẹjọ́ níwájú àwọn aláìgbàgbọ́.! |
| 7 |
| Ǹjẹ́ nísinsinyìí, àbùkù ni fún un yín pátapáta pé ẹ̀yin ń bá ara yín ṣe ẹjọ́. Kí ní ṣe tí ẹ kò kúkú gba ìyà? Kí ní dé tí ẹ kò kúkú gba ìrẹ́jẹ kí ẹ sì fi i sílẹ̀ bẹ́ẹ̀? |
| 8 |
| Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ń jẹ ni ní ìyà, ẹ sì ń rẹ́ ni jẹ. Ẹ̀yin si ń ṣe èyí sí àwọn arákùnrin yín. |
| 9 |
| Ẹ̀yin kò mọ̀ pé àwọn aláìsòótọ́ kì í yóò jogún ìjọba Ọlọ́run? Kí a máa tàn yín jẹ; kì í ṣe àwọn àgbèrè, tàbí àwọn abọ̀rìṣà, tàbí àwọn panṣágà, tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ṣe ìṣe obìnrin tàbí àwọn ọkùnrin tí ń ba ara wọn lòpọ̀ |
| 10 |
| tàbí àwọn olè, tàbí àwọn wọ̀bìà, tàbí àwọn ọ̀mútí, tàbí àwọn apẹ̀gàn, tàbí àwọn alọ́nilọ́wọ́gbà ni yóò jogún ìjọba Ọlọ́run. |
| 11 |
| Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlòmíràn nínú yín sì tí jẹ́ rí; ṣùgbọ̀n a ti sọ yín di mímọ́, ṣùgbọ́n a ti dá yín láre ni orúkọ Jésù Kírísítì Olúwa, àti nípa Ẹ̀mí Mímọ́ Ọlọ́run wa. |
| 12 |
| “Ohun gbogbo ní ó yẹ fún mi,” ṣùgbọ́n kì í ṣe ohun gbogbo ni ó ní èrè; “Ohun gbogbo ni ó yẹ fún mi,” ṣùgbọ́n èmi kì yóò jẹ́ kí a fi mi ṣe olórí ohunkóhun. |
| 13 |
| “Oúnjẹ fún inú àti inú fún oúnjẹ,” ṣùgbọ́n Ọlọ́run yóò fi òpin sí méjèèjì, ara kì í ṣe fún ìwà àgbérè síṣe, ṣùgbọ́n fún Olúwa, àti Olúwa fún ara náà. |
| 14 |
| Nínú agbára rẹ̀, Ọlọ́run jí Olúwa dìde kúrò nínú òkú bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni yóò jí àwa náà dìde. |
| 15 |
| Ṣé ẹ kò tilẹ̀ mọ̀ pé ara yín gan an jẹ́ ẹ̀yà ara Kírísítì fún ara rẹ̀? Ǹjẹ́ tí ó ba jẹ́ bẹ́ẹ̀, ǹjẹ́ ó yẹ kí ń mú ẹ̀yà ara Kírísítì kí ń fi ṣe ẹ̀yá ara àgbérè bí? Kí a má rí i! |
| 16 |
| Tàbí ẹ kò mọ̀ pé bí ẹnìkan bá so ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ àgbérè ó jẹ́ ara kan pẹ̀lú rẹ̀? Nítorí a tí kọ ọ́ wí pé, “Àwọn méjèèjì ni yóò di ara kan ṣoṣo.” |
| 17 |
| Ṣùgbọ́n ẹni ti ó dápọ̀ mọ́ Olúwa di ẹ̀mí kan náà pẹ̀lú rẹ̀. |
| 18 |
| Ẹ máa sá fún àgbérè. Gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ènìyàn ń dá wà lóde ara, ṣùgbọ́n ẹni tí ń ṣe àgbérè ń ṣe sí ara òun tìká ara rẹ̀. |
| 19 |
| Tàbí, ẹ̀yin kò mọ̀ pé ara yín ni tẹ́ḿpìlì Ẹ̀mí Mímọ́, ti ń bẹ nínú yín, ti ẹ̀yin ti gbà lọ́wọ́ Ọlọ́run? Ẹ̀yin kì í ṣe ti ara yín, |
| 20 |
| nítorí a ti rà yín ni iye kan; Nítorí náà ẹ yìn Ọlọ́run lógo nínú ara yín, àti nínú ẹ̀mí yín, tì í ṣe ti Ọlọ́run. |
|
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba2014/1corinthians/006.mp3
16
6