AWỌN alufa, awọn ọmọ Lefi, ani gbogbo ẹ̀ya Lefi, ki yio ní ipín tabi iní pẹlu Israeli: ki nwọn ki o ma jẹ ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe, ati iní rẹ̀ ni ki nwọn ki o ma jẹ.
Eyi ni yio si ma jẹ́ ipín awọn alufa lati ọdọ awọn enia wá, lati ọdọ awọn ti o ru ẹbọ, iba ṣe akọ-malu tabi agutan, ki nwọn ki o si fi apa fun alufa, ati ẹrẹkẹ mejeji ati àpo.
Ki a máṣe ri ninu nyin ẹnikan ti nmu ọmọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọ rẹ̀ obinrin là iná já, tabi ti nfọ̀ afọ̀ṣẹ, tabi alakiyesi-ìgba, tabi aṣefàiya, tabi ajẹ́,
Gẹgẹ bi gbogbo eyiti iwọ bère lọwọ OLUWA Ọlọrun rẹ ni Horebu li ọjọ́ ajọ nì, wipe, Máṣe jẹ ki emi tun gbọ́ ohùn OLUWA Ọlọrun mi mọ́, bẹ̃ni ki emi ki o má tun ri iná nla yi mọ́; ki emi ki o mà ba kú.
Nigbati wolĩ kan ba sọ̀rọ li orukọ OLUWA, bi ohun na kò ba ri bẹ̃, ti kò ba si ṣẹ, eyinì li ohun ti OLUWA kò sọ: wolĩ na li o fi ikùgbu sọ̀rọ: ki iwọ ki o máṣe bẹ̀ru rẹ̀.