BI ọkunrin kan ba fẹ́ obinrin kan, ti o si gbé e niyawo, yio si ṣe, bi obinrin na kò ba ri ojurere li oju ọkunrin na, nitoriti o ri ohun alebù kan lara rẹ̀: njẹ ki o kọ iwé ikọsilẹ fun obinrin na, ki o fi i lé e lọwọ, ki o si rán a jade kuro ninu ile rẹ̀.
Bi ọkọ rẹ̀ ikẹhin ba si korira rẹ̀, ti o si kọ iwé ikọsilẹ fun u, ti o si fi i lé e lọwọ, ti o si rán a jade kuro ninu ile rẹ̀; tabi bi ọkọ ikẹhin ti o fẹ́ ẹ li aya ba kú;
Ọkọ rẹ̀ iṣaju, ti o rán a jade kuro, ki o máṣe tun ní i li aya lẹhin ìgba ti o ti di ẹni-ibàjẹ́ tán; nitoripe irira ni niwaju OLUWA: iwọ kò si gbọdọ mu ilẹ na ṣẹ̀, ti OLUWA Ọlọrun rẹ fi fun ọ ni iní.
Bi ọkunrin kan ba gbé iyawo titun, ki o máṣe lọ si ogun, bẹ̃ni ki a máṣe fun u ni iṣẹkiṣẹ kan ṣe: ki o ri àye ni ile li ọdún kan, ki o le ma mu inu aya rẹ̀ ti o ní dùn.
Bi a ba mú ọkunrin kan ti njí ẹnikan ninu awọn arakunrin rẹ̀, awọn ọmọ Israeli, ti o nsìn i bi ẹrú, tabi ti o tà a; njẹ olè na o kú; bẹ̃ni iwọ o mú ìwabuburu kuro lãrin nyin.
Ma kiyesi àrun-ẹ̀tẹ, ki iwọ ki o ṣọra gidigidi ki o si ṣe gẹgẹ bi gbogbo eyiti awọn alufa awọn ọmọ Lefi yio ma kọ́ nyin: bi emi ti pa a laṣẹ fun wọn, bẹ̃ni ki ẹnyin ki o ma kiyesi lati ṣe.
Bi o ti wù ki o ri iwọ kò gbọdọ má mú ògo rẹ̀ pada fun u, nigbati õrùn ba nwọ̀, ki on ki o le ri aṣọ bora sùn, ki o si sure fun ọ: ododo ni yio si jasi fun ọ niwaju OLUWA Ọlọrun rẹ.
Ni ọjọ́ rẹ̀, ni ki iwọ ki o sanwo ọ̀ya rẹ̀ fun u, bẹ̃ni ki o máṣe jẹ ki õrùn ki o wọ̀ bá a; nitoripe talakà li on, o si gbẹkẹ rẹ̀ lé e: ki o má ba kepè OLUWA si ọ, a si di ẹ̀ṣẹ si ọ lọrùn.
Nigbati iwọ ba kore rẹ li oko rẹ, ti iwọ ba si gbagbé ití-ọkà kan silẹ ninu oko, ki iwọ ki o máṣe pada lọ mú u: ki o le ma jẹ́ ti alejò, ti alainibaba, ati ti opó: ki OLUWA Ọlọrun rẹ ki o le ma busi i fun ọ, ninu iṣẹ ọwọ́ rẹ gbogbo.