Gbọ́, ìwọ Ísírẹ́lì. Báyìí, ẹ ti gbáradì látí la Jọ́dánì kọjá, láti lọ gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀ èdè tí wọ́n tóbi, tí wọ́n sì lágbára jù yín lọ, tí wọ́n ní àwọn ìlú ńláńlá, tí odi wọn kan ọ̀run.
Àwọn ènìyàn náà lágbára wọ́n sì ga àní àwọn ọmọ Ánákì ni wọ́n. Ẹ gbọ́ nípa wọn, ẹ sì gbọ́ tí àwọn ènìyàn ń sọ nípa wọn pé, “Ta ni ó le è dojú ìjà kọ àwọn ọmọ Ánákì (Òmìrán)?”
Ṣùgbọ́n kí ó dá a yín lójú lónìí pé OLÚWA Ọlọ́run yín ni ó ń ṣáájú u yín lọ gẹ́gẹ́ bí iná ajónirun. Yóò jó wọn run, yóò sì tẹ orí wọn ba níwájú yín. Ẹ ó sì lé wọ́n jáde, ẹ ó sì run wọ́n kíákíá, bí OLÚWA ti ṣèlérí fún un yín.
Lẹ́yìn tí OLÚWA Ọlọ́run yín bá ti lé wọn jáde níwájú u yín, ẹ má ṣe wí fún ara yín pé, “Torí òdodo mi ní OLÚWA se mú mi wá síbí láti gba ilẹ̀ náà.” Rárá, ṣùgbọ́n nítorí ìwà búburú àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí ni Ọlọ́run yóò se lé wọn jáde níwájú u yín.
Kì í se nítorí òdodo yín, tàbí ìdúróṣinṣin ni ẹ ó fí wọ ìlú wọn lọ láti gba ilẹ̀ wọn, ṣùgbọ́n nítorí ìwà búburú àwọn orílẹ̀ èdè wọ̀nyí ni OLÚWA Ọlọ́run yín yóò fi lé wọn jáde kúrò níwájú u yín láti lè mú ohun tí ó búra fún àwọn baba ṣẹ: fún Ábúráhámù, Ísáákì àti Jákọ́bù.
Ẹ rántí, ẹ má sì ṣe gbàgbé bí ẹ ti mú OLÚWA Ọlọ́run yín bínú ní ihà. Láti ọjọ́ ti ẹ tí kúrò ní Éjíbítì ni ẹ ti ń ṣọ̀tẹ̀ sí OLÚWA títí tí ẹ fi dé ìhín yìí.
Nígbà tí mo gòkè lọ láti lọ gba sílétì òkúta, sílétì májẹ̀mú ti OLÚWA ti bá a yín dá. Ogójì ọ̀sán àti òru ni mo fi wà lórí òkè náà, èmi kò fẹnu kan oúnjẹ bẹ́ẹ̀ ni ń kò mumi.
Bẹ́ẹ̀ ni OLÚWA sọ fún mi pé, “Sọ̀kalẹ̀ kúrò níhìnín kíákíá, torí pé àwọn ènìyàn rẹ tí o mú jáde láti Éjíbítì ti hùwà ìbàjẹ́. Wọ́n ti yípadà kíá, nínú àṣẹ mi, wọ́n sì ti ṣe ère dídá fún ara wọn.”
Gbà tí mo ṣàkíyèsí, mo rí i pé ẹ ti dẹ́sẹ̀ sí OLÚWA Ọlọ́run yín. Ẹ ti ṣe ère òrìṣà ní ìrí ọ̀dọ́ màlúù, fún ara yín. Ẹ ti yípadà kánkán kúrò nínú ọ̀nà tí OLÚWA ti pàṣẹ fún un yín.
Lẹ́yìn náà mo tún wólẹ̀ níwájú OLÚWA fún ogójì ọ̀sán àti ogójì òru: Èmi kò jẹ oúnjẹ kankan bẹ́ẹ̀ ni èmi kò mu omi, nítorí gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí ẹ tí dá, tí ẹ sì ń ṣe búburú lójú OLÚWA, tí ẹ sì ń mú u bínú.
Bẹ́ẹ̀ ni mo sì mú ohun tí ó mú un yín dẹ́sẹ̀, àní ère òrìṣà màlúù tí ẹ ti ṣe, mo sì fi iná sun ún, bẹ́ẹ̀ ni mo gún un, mo sì lọ̀ ọ́ lúúlúú bí eruku lẹ́búlẹ́bú, mo sì da ẹ̀lọ̀ rẹ̀ sínú odò tí ń sàn níṣàlẹ̀ òkè.
Nígbà tí OLÚWA ran an yín jáde ní Kadesi Báníyà, Ó wí pé, “Ẹ gòkè lọ, kí ẹ sì gba ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín.” Ṣùgbọ́n ẹ sọ̀tẹ̀ sí òfin OLÚWA Ọlọ́run yín. Ẹ kò gbẹ́kẹ̀lé e, bẹ́ẹ̀ ni ẹ kò gbọ́ tirẹ̀.
Mo gbàdúrà sí OLÚWA wí pé, “OLÚWA Olódùmarè, má ṣe run àwọn ènìyàn rẹ, àní ogún rẹ tí o ti ràpadà, nípa agbára rẹ tí o sì fi agbára ńlá mú wọn jáde láti Éjíbítì wá.
Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, orílẹ̀ èdè tí ìwọ ti mú wa jáde wá yóò wí pé, ‘Torí pé OLÚWA kò lè mú wọn lọ sí ilẹ̀ náà tí ó ti ṣèlérí fún wọn, àti pé ó ti kórìíra wọn, ni ó fi mú wọn jáde láti pa wọ́n ní ihà.’