Ti nwọn si ti ṣubu kuro, ko le ṣe iṣe lati sọ wọn di ọtun si ironupiwada, nitori nwọn tún kàn Ọmọ Ọlọrun mọ agbelebu si ara wọn li ọtun, nwọn si dojutì i ni gbangba.
Nitori ilẹ ti o fi omi ojò ti nrọ̀ sori rẹ̀ nigbagbogbo mu, ti o si nhù ewebẹ ti o dara fun awọn ti a nti itori wọn ro o pẹlu, ngbà ibukún lọwọ Ọlọrun.
Nitori Ọlọrun kì iṣe alaiṣododo ti yio fi gbagbé iṣẹ nyin ati ifẹ ti ẹnyin fihàn si orukọ rẹ̀, nipa iṣẹ iranṣẹ ti ẹ ti ṣe fun awọn enia mimọ́, ti ẹ si nṣe.
Pe, nipa ohun aileyipada meji, ninu eyiti ko le ṣe iṣe fun Ọlọrun lati ṣeke, ki awa ti o ti sá sabẹ ãbo le ni ìṣírí ti o daju lati dì ireti ti a gbé kalẹ niwaju wa mu: