Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| IPÍN awọn ọmọ Josefu yọ lati Jordani lọ ni Jeriko, ni omi Jeriko ni ìha ìla-õrùn, ani aginjù, ti o gòke lati Jeriko lọ dé ilẹ òke Beti-eli; |
| 2 |
| O si ti Beti-eli yọ si Lusi, o si kọja lọ si àgbegbe Arki dé Atarotu; |
| 3 |
| O si sọkalẹ ni ìha ìwọ-õrùn si àgbegbe Jafleti, dé àgbegbe Beti-horoni isalẹ, ani dé Geseri: o si yọ si okun. |
| 4 |
| Bẹ̃li awọn ọmọ Josefu, Manasse ati Efraimu, gbà ilẹ-iní wọn. |
| 5 |
| Àla awọn ọmọ Efraimu gẹgẹ bi idile wọn li eyi: ani àla ilẹ-iní wọn ni ìha ìla-õrùn ni Atarotu-adari, dé Beti-horoni òke; |
| 6 |
| Àla na si lọ si ìha ìwọ-õrùn si ìha ariwa Mikmeta; àla na si yi lọ si ìha ìla-õrùn dé Taanati-ṣilo, o si kọja lẹba rẹ̀ lọ ni ìha ìla-õrùn Janoha; |
| 7 |
| O si sọkalẹ lati Janoha lọ dé Atarotu, ati dé Naara, o si dé Jeriko, o si yọ si Jordani. |
| 8 |
| Àla na jade lọ lati Tappua si ìha ìwọ-õrùn titi dé odò Kana; o si yọ si okun. Eyi ni ilẹ-iní ẹ̀ya awọn ọmọ Efraimu gẹgẹ bi idile wọn; |
| 9 |
| Pẹlu ilu ti a yàsọtọ fun awọn ọmọ Efraimu lãrin ilẹ-iní awọn ọmọ Manasse, gbogbo ilu na pẹlu ileto wọn. |
| 10 |
| Nwọn kò si lé awọn ara Kenaani ti ngbé Geseri jade: ṣugbọn awọn ara Kenaani joko lãrin Efraimu titi di oni yi, nwọn si di ẹrú lati ma sìnru. |
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/joshua/016.mp3
24
16