Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| NIGBANA ni awọn olori awọn baba awọn ọmọ Lefi sunmọ Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati awọn olori awọn baba ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli; |
| 2 |
| Nwọn si wi fun wọn ni Ṣilo ni ilẹ Kenaani pe, OLUWA palaṣẹ lati ọwọ́ Mose wá lati fun wa ni ilu lati ma gbé, ati àgbegbe wọn fun ohun-ọ̀sin wa. |
| 3 |
| Awọn ọmọ Israeli si fi ilu wọnyi pẹlu àgbegbe wọn fun awọn ọmọ Lefi ninu ilẹ-iní wọn, nipa aṣẹ OLUWA. |
| 4 |
| Ipín si yọ fun idile awọn ọmọ Kohati: ati awọn ọmọ Aaroni alufa, ti mbẹ ninu awọn ọmọ Lefi, fi keké gbà ilu mẹtala, lati inu ẹ̀ya Juda, ati lati inu ẹ̀ya Simeoni, ati lati inu ẹ̀ya Benjamini. |
| 5 |
| Awọn ti o kù ninu awọn ọmọ Kohati, fi keké gbà ilu mẹwa lati inu idile ẹ̀ya Efraimu, ati lati inu ẹ̀ya Dani, ati lati inu àbọ ẹ̀ya Manasse. |
| 6 |
| Awọn ọmọ Gerṣoni si fi keké gbà ilu mẹtala, lati inu idile ẹ̀ya Issakari, ati ninu ẹ̀ya Aṣeri, ati lati inu ẹ̀ya Naftali, ati inu àbọ ẹ̀ya Manasse ni Baṣani. |
| 7 |
| Awọn ọmọ Merari gẹgẹ bi idile wọn, ní ilu mejila, lati inu ẹ̀ya Reubeni, ati inu ẹ̀ya Gadi, ati lati inu ẹ̀ya Sebuluni. |
| 8 |
| Awọn ọmọ Israeli fi keké fun awọn ọmọ Lefi ni ilu wọnyi pẹlu àgbegbe wọn, gẹgẹ bi OLUWA ti palaṣẹ lati ọwọ́ Mose wá. |
| 9 |
| Nwọn si fi ilu ti a darukọ wọnyi fun wọn, lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Juda, ati lati inu ẹ̀ya awọn ọmọ Simeoni wá: |
| 10 |
| Nwọn si jẹ́ ti awọn ọmọ Aaroni, ni idile awọn ọmọ Kohati, ti mbẹ ninu awọn ọmọ Lefi, nitoriti nwọn ní ipín ikini. |
| 11 |
| Nwọn si fi Kiriati-arba, ti iṣe Hebroni fun wọn, (Arba ni baba Anaki ni ilẹ òke Juda,) pẹlu àgbegbe rẹ̀ yi i kakiri. |
| 12 |
| Ṣugbọn pápa ilu na, ati ileto rẹ̀, ni nwọn fi fun Kalebu ọmọ Jefunne ni ilẹ-iní rẹ̀. |
| 13 |
| Nwọn si fi Hebroni ilu àbo fun apania pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Libna pẹlu àgbegbe rẹ̀, fun awọn ọmọ Aaroni alufa; |
| 14 |
| Ati Jatiri pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Eṣtemoa pẹlu àgbegbe rẹ̀; |
| 15 |
| Ati Holoni pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Debiri pẹlu àgbegbe rẹ̀; |
| 16 |
| Ati Aini pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Jutta pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Beti-ṣemeṣi pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹsan ninu awọn ẹ̀ya meji wọnni. |
| 17 |
| Ati lati inu ẹ̀ya Benjamini, Gibeoni pẹlu àgbegbe rẹ̀, Geba pẹlu àgbegbe rẹ̀; |
| 18 |
| Anatotu pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Almoni pelu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin. |
| 19 |
| Gbogbo ilu awọn ọmọ Aaroni, awọn alufa, jẹ́ ilu mẹtala pẹlu àgbegbe wọn. |
| 20 |
| Ati idile awọn ọmọ Kohati, awọn ọmọ Lefi, ani awọn ọmọ Kohati ti o kù, nwọn ní ilu ti iṣe ipín ti wọn lati inu ẹ̀ya Efraimu. |
| 21 |
| Nwọn si fi Ṣekemu fun wọn pẹlu àgbegbe rẹ̀, ni ilẹ òke Efraimu, ilu àbo fun apania, ati Geseri pẹlu àgbegbe rẹ̀; |
| 22 |
| Ati Kibsaimu pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Beti-horoni pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin. |
| 23 |
| Ati ninu ẹ̀ya Dani, Elteke pẹlu àgbegbe rẹ̀, Gibbetoni pẹlu àgbegbe rẹ̀; |
| 24 |
| Aijaloni pẹlu àgbegbe rẹ̀, Gati-rimmoni pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin. |
| 25 |
| Ati ninu àbọ ẹ̀ya Manasse, Taanaki pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Gati-rimmoni pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu meji. |
| 26 |
| Gbogbo ilu na jasi mẹwa pẹlu àgbegbe wọn fun idile awọn ọmọ Kohati ti o kù. |
| 27 |
| Ati awọn ọmọ Gerṣoni, idile awọn ọmọ Lefi, ni nwọn fi Golani ni Baṣani fun pẹlu àgbegbe rẹ̀, ilu àbo fun apania; lati inu ẹ̀ya Manasse, ati Be-eṣtera pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu meji. |
| 28 |
| Ati ninu ẹ̀ya Issakari, Kiṣioni pẹlu àgbegbe rẹ̀, Dabarati pẹlu àgbegbe rẹ̀; |
| 29 |
| Jarmutu pẹlu àgbegbe rẹ̀, Engannimu pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin. |
| 30 |
| Ati ninu ẹ̀ya Aṣeri, Miṣali pẹlu àgbegbe rẹ̀, Abdoni pẹlu àgbegbe rẹ̀; |
| 31 |
| Helkati pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Rehobu pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin. |
| 32 |
| Ati lati inu ẹ̀ya Naftali, Kedeṣi ni Galili pẹlu àgbegbe rẹ̀, ilu àbo fun apania; ati Hammotu-dori pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Kartani pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹta. |
| 33 |
| Gbogbo ilu awọn ọmọ Gerṣoni gẹgẹ bi idile wọn, jẹ́ ilu mẹtala pẹlu ileto wọn. |
| 34 |
| Ati fun idile awọn ọmọ Merari, awọn ọmọ Lefi ti o kù, ni Jokneamu pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Karta pẹlu àgbegbe rẹ̀, lati inu ẹ̀ya Sebuluni, |
| 35 |
| Dimna pẹlu àgbegbe rẹ̀, Nahalali pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin. |
| 36 |
| Ati ninu ẹ̀ya Reubeni, Beseri pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Jahasi pẹlu àgbegbe rẹ̀, |
| 37 |
| Kedemotu pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Mefaati pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin. |
| 38 |
| Ati ninu ẹ̀ya Gadi, Ramotu ni Gileadi pẹlu àgbegbe rẹ̀, ilu àbo fun apania; ati Mahanaimu pẹlu àgbegbe rẹ̀. |
| 39 |
| Heṣboni pẹlu àgbegbe rẹ̀, Jaseri pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin ni gbogbo rẹ̀. |
| 40 |
| Gbogbo wọnyi ni ilu awọn ọmọ Merari, gẹgẹ bi idile wọn, ani awọn ti o kù ni idile awọn ọmọ Lefi; ipín wọn si jẹ́ ilu mejila. |
| 41 |
| Gbogbo ilu awọn ọmọ Lefi ti mbẹ lãrin ilẹ-iní awọn ọmọ Israeli jẹ́ ilu mejidilãdọta pẹlu àgbegbe wọn. |
| 42 |
| Olukuluku ilu wọnyi li o ní àgbegbe wọn yi wọn ká: bayi ni gbogbo ilu wọnyi ri. |
| 43 |
| OLUWA si fun Israeli ni gbogbo ilẹ na, ti o bura lati fi fun awọn baba wọn; nwọn si gbà a, nwọn si ngbé inu rẹ̀. |
| 44 |
| OLUWA si fun wọn ni isimi yiká kiri, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o bura fun awọn baba wọn: kò si sí ọkunrin kan ninu gbogbo awọn ọtá wọn ti o duro niwaju wọn; OLUWA fi gbogbo awọn ọtá wọn lé wọn lọwọ. |
| 45 |
| Ohunkohun kò tase ninu ohun rere ti OLUWA ti sọ fun ile Israeli; gbogbo rẹ̀ li o ṣẹ. |
|
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/joshua/021.mp3
24
21