|
| 1 |
| ALÀGBA si Gaiu olufẹ, ẹniti mo fẹ ninu otitọ. |
| 2 |
| Olufẹ, emi ngbadura pe ninu ohun gbogbo ki o le mã dara fun ọ, ki o si mã wà ni ilera, ani bi o ti dara fun ọkàn rẹ. |
| 3 |
| Nitori mo yọ̀ gidigidi, nigbati awọn arakunrin de ti nwọn si jẹri si otitọ rẹ, ani bi iwọ ti nrìn ninu otitọ. |
| 4 |
| Emi kò ni ayọ̀ ti o pọjù eyi lọ, ki emi ki o mã gbọ́ pe, awọn ọmọ mi nrìn ninu otitọ. |
| 5 |
| Olufẹ, iwọ nṣe iṣẹ igbagbọ li ohunkohun ti o bá nṣe fun awọn ti iṣe ará ati fun awọn alejò; |
| 6 |
| Ti nwọn jẹri ifẹ rẹ niwaju ijọ: bi ìwọ bá npese fun wọn li ọna ajo wọn bi o ti yẹ nipa ti Ọlọrun, iwọ o ṣe ohun ti o dara. |
| 7 |
| Nitoripe nitori orukọ rẹ̀ ni nwọn ṣe jade lọ, li aigbà ohunkohun lọwọ awọn Keferi. |
| 8 |
| Njẹ o yẹ ki awa ki o gbà irú awọn wọnni, ki awa ki o le jẹ́ alabaṣiṣẹpọ pẹlu otitọ. |
| 9 |
| Emi kọwe si ijọ: ṣugbọn Diotrefe, ẹniti o fẹ lati jẹ olori larin wọn, kò gbà wa. |
| 10 |
| Nitorina bi mo ba de, emi o mu iṣẹ rẹ̀ ti o ṣe wá si iranti, ti o nsọ ọrọ buburu ati isọkusọ si wa: eyini kò si tẹ́ ẹ lọrùn, bẹ̃ni on tikararẹ̀ kò gbà awọn ará, awọn ti o si nfẹ gbà wọn, o ndá wọn lẹkun, o si nlé wọn jade kuro ninu ijọ. |
| 11 |
| Olufẹ, máṣe afarawe ohun ti iṣe ibi, bikoṣe ohun ti iṣe rere. Ẹniti o ba nṣe rere ti Ọlọrun ni: ẹniti o ba nṣe buburu kò ri Ọlọrun. |
| 12 |
| Demetriu li ẹri rere lọdọ gbogbo enia ati ti otitọ tikararẹ̀ pẹlu: nitõtọ, awa pẹlu si gbà ẹrí rẹ̀ jẹ; ẹnyin si mọ̀ pe otitọ ni ẹrí wa. |
| 13 |
| Emi ní ohun pupọ̀ lati kọwe si ọ, ṣugbọn emi kò fẹ fi tàdãwa on kalamu kọ wọn. |
| 14 |
| Ṣugbọn mo ni ireti lati ri ọ laipẹ, a o si sọrọ li ojukoju. |
| 15 |
| Alafia fun ọ. Awọn ọrẹ́ kí ọ. Kí awọn ọrẹ́ li ọkọ̃kan. |
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/3john/001.mp3
1
1