Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| A si fi ifefe kan fun mi ti ó dabi ọpá: o wipe, Dide, si wọ̀n tẹmpili Ọlọrun, ati pẹpẹ, ati awọn ti nsìn ninu rẹ̀; |
| 2 |
| Si fi agbala ti mbẹ lode tẹmpili silẹ, má si ṣe wọ̀n ọ; nitoriti a fi i fun awọn Keferi: ilu mimọ́ na li nwọn o si tẹ̀ mọlẹ li oṣu mejilelogoji. |
| 3 |
| Emi o si yọnda fun awọn ẹlẹri mi mejeji, nwọn ó si sọtẹlẹ fun ẹgbẹfa ọjọ o le ọgọta ninu aṣọ-ọfọ. |
| 4 |
| Wọnyi ni igi oróro meji nì, ati ọpá fitila meji nì, ti nduro niwaju Oluwa aiye. |
| 5 |
| Bi ẹnikẹni ba si fẹ pa wọn lara, iná a ti ẹnu wọn jade, a si pa awọn ọtá wọn run: bi ẹnikẹni yio ba si fẹ pa wọn lara, bayi li o yẹ ki a pa a. |
| 6 |
| Awọn wọnyi li o ni agbara lati sé ọrun, ti ojo kò fi rọ̀ li ọjọ asọtẹlẹ wọn: nwọn si ni agbara lori omi lati sọ wọn di ẹ̀jẹ, ati lati fi oniruru ajakalẹ arun kọlu aiye, nigbakugba ti nwọn ba fẹ. |
| 7 |
| Nigbati nwọn ba si ti pari ẹrí wọn, ẹranko ti o nti inu ọ̀gbun goke wá ni yio ba wọn jagun, yio si ṣẹgun wọn, yio si pa wọn. |
| 8 |
| Okú wọn yio si wà ni igboro ilu nla nì, ti a npè ni Sodomu ati Egipti nipa ti ẹmí, nibiti a gbé kàn Oluwa wọn mọ agbelebu. |
| 9 |
| Ati ninu awọn enia, ati ẹya, ati ède, ati orilẹ, nwọn wo okú wọn fun ijọ mẹta on àbọ, nwọn kò si jẹ ki a gbé okú wọn sinu isà okú. |
| 10 |
| Ati awọn ti o ngbé ori ilẹ aiye yio si yọ̀ le wọn lori, nwọn si ṣe ariya, nwọn o si ta ara wọn lọrẹ; nitoriti awọn woli mejeji yi dá awọn ti o mbẹ lori ilẹ aiye loró. |
| 11 |
| Ati lẹhin ijọ mẹta on àbọ na, ẹmí ìye lati ọdọ Ọlọrun wá wọ̀ inu wọn, nwọn si dide duro li ẹsẹ wọn; ẹ̀ru nla si ba awọn ti o ri wọn. |
| 12 |
| Nwọn si gbọ́ ohùn nla kan lati ọrun wá nwi fun wọn pe, Ẹ gòke wá ìhin. Nwọn si gòke lọ si ọrun ninu awọsanma; awọn ọtá wọn si ri wọn. |
| 13 |
| Ni wakati na ìṣẹlẹ nla ṣẹ̀, idamẹwa ilu na si wó, ati ninu ìṣẹlẹ na ẹdẹgbarin enia li a pa: ẹ̀ru si ba awọn iyokù, nwọn si fi ogo fun Ọlọrun ọrun. |
| 14 |
| Egbé keji kọja; si kiyesi i, egbé kẹta si mbọ̀wá kánkán. |
| 15 |
| Angẹli keje si fun ipè; a si gbọ́ ohùn nla lati ọrun wá, wipe, Ijọba aiye di ti Oluwa wa, ati ti Kristi rẹ̀; on o si jọba lai ati lailai. |
| 16 |
| Awọn àgba mẹrinlelogun nì ti nwọn joko niwaju Ọlọrun lori ítẹ wọn, dojubolẹ, nwọn si sìn Ọlọrun, |
| 17 |
| Wipe, Awa fi ọpẹ́ fun ọ, Oluwa Ọlọrun, Olodumare, ti mbẹ, ti o si ti wà, ti o si ma bọ̀; nitoriti iwọ ti gbà agbara nla rẹ, iwọ si ti jọba. |
| 18 |
| Inu si bi awọn orilẹ-ède, ibinu rẹ si de, ati ìgba lati dá awọn okú lẹjọ, ati lati fi ere fun awọn iranṣẹ rẹ woli ati awọn enia mimọ́ ati awọn ti o bẹ̀ru orukọ rẹ, ati ẹni kekere ati ẹni nla; ati lati run awọn ti npa aiye run. |
| 19 |
| A si ṣí tẹmpili Ọlọrun silẹ li ọrun, a si ri apoti majẹmu ninu tẹmpili rẹ̀: mànamána si kọ, a si gbọ ohùn, ãrá si san, ìṣẹlẹ si ṣẹ̀, yinyín nla si bọ. |
|
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/revelation/011.mp3
22
11