Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| O si duro lori iyanrìn okun, mo si ri ẹranko kan nti inu okun jade wá, o ni ori meje ati iwo mẹwa, ati ade mẹwa lori awọn iwo na, ati li awọn ori rẹ̀ na ni orukọ ọrọ-odi. |
| 2 |
| Ẹranko ti mo ri na si dabi ẹkùn, ẹsẹ rẹ̀ si dabi ti beari, ẹnu rẹ̀ si dabi ti kiniun: dragoni na si fun u li agbara rẹ̀, ati itẹ rẹ̀, ati ọlá nla. |
| 3 |
| Mo si ri ọkan ninu awọn ori rẹ̀ bi ẹnipe a sá a pa, a si ti wo ọgbẹ aṣapa rẹ̀ na san, gbogbo aiye si fi iyanu tẹle ẹranko na. |
| 4 |
| Nwọn si foribalẹ fun dragoni na nitori o ti fun ẹranko na ni ọla: nwọn si foribalẹ fun ẹranko na, wipe, Tali o dabi ẹranko yi? tali o si le ba a jagun? |
| 5 |
| A si fun u li ẹnu lati mã sọ ohun nla ati ọrọ-odi; a si fi agbara fun u lati ṣe bẹ ẹ ni oṣu mejilelogoji. |
| 6 |
| O si yà ẹnu rẹ̀ ni isọrọ̀-odi si Ọlọrun, lati sọ ọrọ-odi si orukọ rẹ̀, ati si agọ́ rẹ̀, ati si awọn ti ngbe ọrun. |
| 7 |
| A si fi fun u lati mã ba awọn enia mimọ́ jagun, ati lati ṣẹgun wọn: a si fi agbara fun u lori gbogbo ẹya, ati enia, ati ède, ati orilẹ. |
| 8 |
| Gbogbo awọn ti ngbe ori ilẹ aiye yio si mã sin i, olukuluku ẹniti a kò kọ orukọ rẹ̀ sinu iwe iyè Ọdọ-Agutan ti a ti pa lati ipilẹṣẹ aiye. |
| 9 |
| Bi ẹnikẹni ba li etí ki o gbọ́. |
| 10 |
| Bi ẹnikẹni ba nfẹ ki a di ẹni igbèkun, igbèkun ni yio lọ: bi ẹnikẹni ba nfẹ ki a fi idà pa ẹni, idà li a o si fi pa on na. Nihin ni sũru ati igbagbọ́ awọn enia mimọ́ gbé wà. |
| 11 |
| Mo si ri ẹranko miran goke lati inu ilẹ wá; o si ni iwo meji bi ọdọ-agutan, o si nsọ̀rọ bi dragoni. |
| 12 |
| O si nlò gbogbo agbara ẹranko ekini niwaju rẹ̀, o si mu ilẹ aiye ati awọn ti ngbe inu rẹ̀ foribalẹ fun ẹranko ekini ti a ti wo ọgbẹ aṣápa rẹ̀ san. |
| 13 |
| O si nṣe ohun iyanu nla, ani ti o fi nmu iná sọkalẹ lati ọrun wá si ilẹ aiye niwaju awọn enia. |
| 14 |
| O si ntàn awọn ti ngbe ori ilẹ aiye jẹ nipa awọn ohun iyanu ti a fi fun u lati ṣe niwaju ẹranko na; o nwi fun awọn ti ngbe ori ilẹ aiye lati ya aworan fun ẹranko na ti o ti gbà ọgbẹ idà, ti o si yè. |
| 15 |
| A si fi fun u lati fi ẹmí fun aworan ẹranko na ki o mã sọ̀rọ, ki o si mu ki a pa gbogbo awọn ti kò foribalẹ fun aworan ẹranko na. |
| 16 |
| O si mu gbogbo wọn, ati kekere ati nla, ọlọrọ̀ ati talakà, omnira ati ẹrú, ki a fi àmi kan fun wọn li ọwọ́ ọtún wọn, tabi ni iwaju wọn: |
| 17 |
| Ati ki ẹnikẹni má le rà tabi ki o tà, bikoṣe ẹniti o bá ni ami orukọ ẹranko na, tabi iye orukọ rẹ̀. |
| 18 |
| Nihin ni ọgbọ́n gbé wà. Ẹniti o ba ni oye, ki o ṣiro iye ti mbẹ lara ẹranko na: nitori iye enia ni; iye rẹ̀ na si jẹ ọ̀talelẹgbẹta o le mẹfa. |
|
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/revelation/013.mp3
22
13