Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| MO si ri àmi miran li ọrun ti o tobi ti o si yanilẹnu, awọn angẹli meje ti o ni awọn iyọnu meje ikẹhin, nitori ninu wọn ni ibinu Ọlọrun de opin. |
| 2 |
| Mo si ri bi ẹnipe òkun digí ti o dàpọ pẹlu iná: awọn ti o si duro lori okun digi yi jẹ awọn ti nwọn ti ṣẹgun ẹranko na, ati aworan rẹ̀, ati ami rẹ̀ ati iye orukọ rẹ̀, nwọn ni dùru Ọlọrun. |
| 3 |
| Nwọn si nkọ orin ti Mose, iranṣẹ Ọlọrun, ati orin ti Ọdọ-Agutan, wipe, Titobi ati iyanu ni awọn iṣẹ rẹ, Oluwa Ọlọrun Olodumare; ododo ati otitọ li ọ̀na rẹ, iwọ Ọba awọn orilẹ-ede. |
| 4 |
| Tani kì yio bẹ̀ru, Oluwa, ti kì yio si fi ogo fun orukọ rẹ? nitori iwọ nikanṣoṣo ni mimọ́: gbogbo awọn orilẹ-ède ni yio si wá, ti yio si foribalẹ niwaju rẹ; nitori a ti fi idajọ rẹ hàn. |
| 5 |
| Lẹhin na mo si wò, si kiyesi i, a ṣí tẹmpili agọ́ ẹrí li ọrun silẹ: |
| 6 |
| Awọn angẹli meje na si ti inu tẹmpili jade wá, nwọn ni iyọnu meje nì, a wọ̀ wọn li aṣọ ọgbọ funfun ti ndan, a si fi àmure wura dì wọn li õkan àiya. |
| 7 |
| Ati ọkan ninu awọn ẹda alãye mẹrin nì fi ìgo wura meje fun awọn angẹli meje na, ti o kún fun ibinu Ọlọrun, ẹniti mbẹ lãye lai ati lailai. |
| 8 |
| Tẹmpili na si kún fun ẹ̃fin lati inu ogo Ọlọrun ati agbara rẹ̀ wá; ẹnikẹni kò si le wọ̀ inu tẹmpili na lọ titi a fi mu iyọnu mejeje awọn angẹli meje na ṣẹ. |
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/revelation/015.mp3
22
15