O si kigbe li ohùn rara, wipe, Babiloni nla ṣubu, o ṣubu, o si di ibujoko awọn ẹmi èṣu, ati ihò ẹmí aimọ́ gbogbo, ati ile ẹiyẹ aimọ́ gbogbo, ati ti ẹiyẹ irira.
Nitori nipa ọti-waini irunu àgbere rẹ̀ ni gbogbo awọn orilẹ-ede ṣubu, awọn ọba aiye si ti ba a ṣe àgbere, ati awọn oniṣowo aiye si di ọlọrọ̀ nipa ọ̀pọlọpọ wọbia rẹ̀.
Mo si gbọ́ ohùn miran lati ọrun wá, nwipe, Ẹ ti inu rẹ̀ jade, ẹnyin enia mi, ki ẹ má bã ṣe alabapin ninu ẹ̀ṣẹ rẹ̀, ki ẹ má bã si ṣe gbà ninu iyọnu rẹ̀.
Niwọn bi o ti yin ara rẹ̀ logo to, ti o si huwa wọbia, niwọn bẹ̃ ni ki ẹ da a loro ki ẹ si fún u ni ibanujẹ: nitoriti o wi li ọkàn rẹ̀ pe, mo joko bi ọbabirin, emi kì si iṣe opó, emi ki yio si ri ibinujẹ lai.
Nwọn o duro li okere rére nitori ibẹru iṣẹ oró rẹ̀, nwọn o mã wipe, Egbé, Egbé ni fun ilu nla na, Babiloni, ilu alagbara ni! nitori ni wakati kan ni idajọ rẹ de.
Ọjà wura, ati ti fadaka, ati ti okuta iyebiye, ati ti perli, ati ti aṣọ ọgbọ wíwe, ati ti elese aluko, ati ti ṣẹ́dà, ati ti ododó, ati ti gbogbo igi olõrun didun, ati ti olukuluku ohun èlo ti ehin-erin, ati ti olukuluku ohun èlo ti a fi igi iyebiye ṣe, ati ti idẹ, ati ti irin, ati ti okuta marbili,
Ati ti kinamoni, ati ti oniruru ohun olõrun didun, ati ti ohun ikunra, ati ti turari, ati ti ọti-waini, ati ti oróro, ati ti iyẹfun daradara, ati ti alikama, ati ti ẹranlá, ati ti agutan, ati ti ẹṣin, ati ti kẹkẹ́, ati ti ẹrú, ati ti ọkàn enìa.
Wipe, Ègbé, egbé ni fun ilu nla nì, ti a wọ̀ li aṣọ ọgbọ wíwẹ, ati ti elese aluko, ati ti ododó, ati ti a si fi wura ṣe lọṣọ́, pẹlu okuta iyebiye ati perli!
Nitoripe ni wakati kan ni ọrọ̀ ti o pọ̀ tobẹ̃ di asan. Ati olukuluku olori ọkọ̀, ati olukuluku ẹniti nrin oju omi lọ si ibikibi, ati awọn ti nṣiṣẹ, ninu ọkọ̀, ati awọn ti nṣowo oju okun duro li òkere rére,
Nwọn si kù ekuru si ori wọn, nwọn kigbe, nwọn sọkun, nwọn si nṣọfọ, wipe, Egbé, Egbé ni fun ilu nla na, ninu eyi ti a sọ gbogbo awọn ti o ni ọkọ̀ li okun di ọlọrọ̀ nipa ohun iyebiye rẹ̀! nitoripe ni wakati kan a sọ ọ di ahoro.
Angẹli alagbara kan si gbé okuta kan soke, o dabi ọlọ nla, o si jù u sinu okun, wipe, Bayi li a o fi agbara nla bì Babiloni ilu nla nì wó, a kì yio si ri i mọ́ lai.
Ati ohùn awọn aludùru, ati ti awọn olorin, ati ti awọn afunfère, ati ti awọn afunpè ni a kì yio si gbọ́ ninu rẹ mọ́ rara; ati olukuluku oniṣọnà ohunkohun ni a kì yio si ri ninu rẹ mọ́ lai; ati iró ọlọ li a kì yio si gbọ́ mọ́ ninu rẹ lai;
Ati imọlẹ fitila ni kì yio si tàn ninu rẹ mọ́ lai; a ki yio si gbọ́ ohùn ọkọ iyawo ati ti iyawo ninu rẹ mọ́ lai: nitoripe awọn oniṣowo rẹ li awọn ẹni nla aiye; nitoripe nipa oṣó rẹ li a fi tàn orilẹ-ède gbogbo jẹ.