Mo si ri angẹli miran ti o nti ìha ìla-õrùn goke wá, ti on ti èdidi Ọlọrun alãye lọwọ: o si kigbe li ohùn rara si awọn angẹli mẹrin na ti a fifun lati pa aiye ati okun lara,
Lati inu ẹ̀ya Aṣeri a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Neftalimu a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Manasse a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa.
Lati inu ẹ̀ya Simeoni a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Lefi a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Issakari a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa.
Lati inu ẹ̀ya Sebuloni a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Josefu a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa. Lati inu ẹ̀ya Benjamini a fi èdidi sami si ẹgbã mẹfa.
Lẹhin na, mo ri, si kiyesi i, ọ̀pọlọpọ enia ti ẹnikẹni kò le kà, lati inu orilẹ-ède gbogbo, ati ẹya, ati enia, ati lati inu ède gbogbo wá, nwọn duro niwaju itẹ́, ati niwaju Ọdọ-Agutan na, a wọ̀ wọn li aṣọ funfun, imọ̀-ọpẹ si mbẹ li ọwọ́ wọn;
Gbogbo awọn angẹli si duro yi itẹ́ na ká, ati yi awọn àgba ati awọn ẹda alãye mẹrin na ká, nwọn wolẹ nwọn si dojubolẹ niwaju itẹ́ na nwọn si sìn Ọlọrun,
Mo si wi fun u pe, Oluwa mi, Iwọ li o le mọ̀. O si wi fun mi pe, Awọn wọnyi li o jade lati inu ipọnju nla, nwọn si fọ̀ aṣọ wọn, nwọn si sọ wọn di funfun ninu ẹ̀jẹ Ọdọ-Agutan na.
Nitori Ọdọ-Agutan ti mbẹ li arin itẹ́ na ni yio mã ṣe oluṣọ-agutan wọn, ti yio si mã ṣe amọna wọn si ibi orisun omi iyè: Ọlọrun yio si nù omije gbogbo nù kuro li oju wọn.