O SI ṣe lẹhin ìgba diẹ, li akokò ikore alikama, Samsoni mú ọmọ ewurẹ kan lọ bẹ̀ aya rẹ̀ wò; on si wipe, Emi o wọle tọ̀ aya mi lọ ni iyẹwu. Ṣugbọn baba obinrin rẹ̀ kò jẹ ki o wọle.
Baba aya rẹ̀ si wipe, Nitõtọ emi ṣebi iwọ korira rẹ̀ patapata ni; nitorina ni mo ṣe fi i fun ẹgbẹ rẹ: aburò rẹ̀ kò ha ṣe arẹwà enia jù on lọ? mo bẹ̀ ọ, mú u dipò rẹ̀.
Nigbati o si ti fi iná si ètufu na, o jọwọ wọn lọ sinu oko-ọkà awọn Filistini, o si kun ati eyiti a dì ni ití, ati eyiti o wà li oró, ati ọgbà-olifi pẹlu.
Nigbana li awọn Filistini wipe, Tani ṣe eyi? Nwọn si dahùn pe, Samsoni, ana ara Timna ni, nitoriti o gbà obinrin rẹ̀, o si fi i fun ẹgbẹ rẹ̀. Awọn Filistini si gòke wá, nwọn si fi iná sun obinrin na ati baba rẹ̀.
Nigbana li ẹgbẹdogun ọkunrin Juda sọkalẹ lọ si palapala apata Etamu, nwọn si wi fun Samsoni, pe, Iwọ kò mọ̀ pe awọn Filistini li alaṣẹ lori wa? kili eyiti iwọ ṣe si wa yi? On si wi fun wọn pe, Gẹgẹ bi nwọn ti ṣe si mi, bẹ̃li emi ṣe si wọn.
Nwọn si wi fun u pe, Awa sọkalẹ wá lati dè ọ, ki awa ki o le fi ọ lé awọn Filistini lọwọ. Samsoni si wi fun wọn pe, Ẹ bura fun mi, pe ẹnyin tikara nyin ki yio pa mi.
Nwọn si wi fun u pe, Rárá o; didè li awa o dè ọ, a o si fi ọ lé wọn lọwọ: ṣugbọn niti pipa awa ki yio pa ọ. Nwọn si fi okùn titun meji dè e, nwọn si mú u gòke lati ibi apata na wá.
Nigbati o dé Lehi, awọn Filistini hó bò o: ẹmi OLUWA si bà lé e, okùn ti o si wà li apa rẹ̀ si wa dabi okùn-ọ̀gbọ ti o ti jóna, ìde rẹ̀ si tú kuro li ọwọ́ rẹ̀.
Ongbẹ si ngbẹ ẹ gidigidi, o si kepè OLUWA, wipe, Iwọ ti fi ìgbala nla yi lé ọmọ-ọdọ rẹ lọwọ: nisisiyi emi o kú nitori ongbẹ, emi o si bọ́ si ọwọ́ awọn alaikọlà.
Ṣugbọn Ọlọrun si là ibi kòto kan ti o wà ni Lehi, nibẹ̀ li omi si sun jade; nigbati on si mu u tán ẹmi rẹ̀ si tun pada, o si sọjí: nitorina ni a ṣe pè orukọ ibẹ̀ na ni Eni-hakkore, ti o wà ni Lehi, titi o fi di oni-oloni.