Bibeli Mimọ Bible 2012
|
| 1 |
| ANGELI OLUWA si ti Gilgali gòke wá si Bokimu. O si wipe, Emi mu nyin gòke lati Egipti wá, emi si mú nyin wá si ilẹ ti emi ti bura fun awọn baba nyin; emi si wipe, Emi ki yio dà majẹmu mi pẹlu nyin lailai: |
| 2 |
| Ẹnyin kò si gbọdọ bá awọn ara ilẹ yi dá majẹmu; ẹnyin o wó pẹpẹ wọn lulẹ: ṣugbọn ẹnyin kò gbọ́ ohùn mi: Ẽha ti ṣe ti ẹnyin fi ṣe yi? |
| 3 |
| Nitorina emi pẹlu wipe, Emi ki yio lé wọn jade kuro niwaju nyin; ṣugbọn nwọn o jẹ́ ẹgún ni ìha nyin, ati awọn oriṣa wọn yio di ikẹkun fun nyin. |
| 4 |
| O si ṣe, nigbati angeli OLUWA sọ ọ̀rọ wọnyi fun gbogbo awọn ọmọ Israeli, awọn enia na si gbé ohùn wọn soke, nwọn si sọkun. |
| 5 |
| Nwọn si pè orukọ ibẹ̀ na ni Bokimu: nwọn si ru ẹbọ nibẹ̀ si OLUWA. |
| 6 |
| Nigbati Joṣua si ti jọwọ awọn enia lọwọ lọ, olukuluku awọn ọmọ Israeli si lọ sinu ilẹ-iní rẹ̀ lati gba ilẹ̀ na. |
| 7 |
| Awọn enia na si sìn OLUWA ni gbogbo ọjọ́ Joṣua, ati ni gbogbo ọjọ́ awọn àgba ti o wà lẹhin Joṣua, awọn ẹniti o ri gbogbo iṣẹ nla OLUWA, ti o ṣe fun Israeli. |
| 8 |
| Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ OLUWA si kú, nigbati o di ẹni ãdọfa ọdún. |
| 9 |
| Nwọn si sinkú rẹ̀ li àla ilẹ-iní rẹ̀ ni Timnati-heresi, ni ilẹ òke Efraimu, li ariwa oke Gaaṣi. |
| 10 |
| Ati pẹlu a si kó gbogbo iran na jọ sọdọ awọn baba wọn: iran miran si hù lẹhin wọn, ti kò mọ̀ OLUWA, tabi iṣẹ ti o ṣe fun Israeli. |
| 11 |
| Awọn ọmọ Israeli si ṣe buburu niwaju OLUWA, nwọn si nsìn Baalimu: |
| 12 |
| Nwọn si kọ̀ OLUWA, Ọlọrun awọn baba wọn silẹ, ti o mú wọn jade lati ilẹ Egipti wá, nwọn si ntọ̀ ọlọrun miran lẹhin, ninu oriṣa awọn enia ti o yi wọn ká kiri, nwọn si nfi ori wọn balẹ fun wọn, nwọn si bi OLUWA ninu. |
| 13 |
| Nwọn si kọ̀ OLUWA silẹ, nwọn si nsìn Baali ati Aṣtarotu. |
| 14 |
| Ibinu OLUWA si rú si Israeli, o si fi wọn lé awọn akonilohun lọwọ, ti o kó wọn lẹrù, o si tà wọn si ọwọ́ awọn ọtá wọn yiká kiri, tobẹ̃ ti nwọn kò le duro mọ́ niwaju awọn ọtá wọn. |
| 15 |
| Nibikibi ti nwọn ba jade lọ, ọwọ́ OLUWA wà lara wọn fun buburu, gẹgẹ bi OLUWA ti wi, ati gẹgẹ bi OLUWA ti bura fun wọn: oju si pọ́n wọn pupọ̀pupọ̀. |
| 16 |
| OLUWA si gbé awọn onidajọ dide, ti o gbà wọn li ọwọ́ awọn ẹniti nkó wọn lẹrù. |
| 17 |
| Sibẹ̀sibẹ nwọn kò fetisi ti awọn onidajọ wọn, nitoriti nwọn ṣe panṣaga tọ̀ ọlọrun miran lẹhin, nwọn si fi ori wọn balẹ fun wọn: nwọn yipada kánkan kuro li ọ̀na ti awọn baba wọn ti rìn, ni gbigbà ofin OLUWA gbọ́; awọn kò ṣe bẹ̃. |
| 18 |
| Nigbati OLUWA ba si gbé awọn onidajọ dide fun wọn, OLUWA a si wà pẹlu onidajọ na, on a si gbà wọn kuro li ọwọ́ awọn ọtá wọn ni gbogbo ọjọ́ onidajọ na: nitoriti OLUWA kãnu, nitori ikerora wọn nitori awọn ti npọ́n wọn loju, ti nwọn si nni wọn lara. |
| 19 |
| O si ṣe, nigbati onidajọ na ba kú, nwọn a si pada, nwọn a si bà ara wọn jẹ́ jù awọn baba wọn lọ, ni titọ̀ ọlọrun miran lẹhin lati ma sìn wọn, ati lati ma fi ori balẹ fun wọn; nwọn kò dẹkun iṣe wọn, ati ìwa-agidi wọn. |
| 20 |
| Ibinu OLUWA si rú si Israeli; o si wipe, Nitoriti orilẹ-ède yi ti re majẹmu mi kọja eyiti mo ti palaṣẹ fun awọn baba wọn, ti nwọn kò si gbọ́ ohùn mi; |
| 21 |
| Emi pẹlu ki yio lé ọkan jade mọ́ kuro niwaju wọn ninu awọn orilẹ-ède, ti Joṣua fisilẹ nigbati o kú: |
| 22 |
| Ki emi ki o le ma fi wọn dan Israeli wò, bi nwọn o ma ṣe akiyesi ọ̀na OLUWA lati ma rìn ninu rẹ̀, bi awọn baba wọn ti ṣe akiyesi rẹ̀, tabi bi nwọn ki yio ṣe e. |
| 23 |
| OLUWA si fi orilẹ-ède wọnni silẹ, li ailé wọn jade kánkan; bẹ̃ni kò si fi wọn lé Joṣua lọwọ. |
|
| Fipamọ Awọn akọsilẹ |
https://beblia.bible:81/BibleAudio/yoruba/judges/002.mp3
21
2